Ìgbéyàwó èmi àti ọkọ mi ti túká àmọ́ irọ́ ni pé mo lu ìyá ọkọ mi – Wunmi Toriola

Wunmi Toriola

Oríṣun àwòrán, Wunmi Toriola/Instagram

Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí ni ẹnu ti ń kun gbajúgbajà òṣèré tíátà, Wunmi Toriola wí pé ìgbéyàwó rẹ̀ ti túká.

Wunmi Toriola ti wá jáde síta báyìí pé lóòótọ́ ni ìgbéyàwó òun pẹ̀lú ọkọ òun ti túká.

Ó ní láti bíi ọdún kan sẹ́yìn ni òun àti ọkọ òun ti pínyà nítorí àwọn kò lè tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò ìfẹ́ àwọn mọ́.

Ó fi kun pé nítorí òun kò fẹ́ ẹjọ́ tàbí wàhálà kankan ni òun kò ṣe fi ìròyìn náà síta tí òun sì ń bá eré àníyàn òun lọ láìsí wàhálà kankan.

Mi ò na ìyá mi tàbí ìyá ọkọ mi o, irọ́ lásán ni

Wunmi Toriola àti ọkọ nígbà ìgbéyàwó wọn

Oríṣun àwòrán, Wunmi Toriola/INSTAGRAM

Wunmi Toriola ní àná ọjọ́ Ajé ni òun rí ìròyìn kan tó gbá orí ayélujára níbi tí wọ́n ti fẹ̀sùn kan òun pé òun lu ìyá òun àti ìyá ọkọ òun.

Toriola ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà àti pé ọkọ òun tẹ́lẹ̀ náà ló hun irọ́ náà jọ láti fi tàbùkù òun.

Ó fi kun pé òun kìí ṣe oníjàgídíjàgan ènìyàn rárá tí òun kìí bá ẹnikẹ́ni jà àti pé kò ní ìtahùnsíra pẹ̀lú ẹnìkankan nítorí jẹ́jẹ́ òun ni òun máa ń lọ.

Bákan náà ló fi kun pé òun kò hùwà ìpáǹle tàbí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ìgbà tí òun fi wà nínú ìgbéyàwó náà.

Ìwà èṣù ni kí ọmọ ṣíwọ́ lu ìyá tó bi lọ́mọ nílẹ̀ Yorùbá

Gbajúmọ̀ òṣèré náà ni ohun tó dun òun jùlọ nínú ìròyìn náà ni pé wọ́n fẹ̀sùn kan òun wí pé òun máa ń na ìyá òun.

Toriola ní ìwà èṣù ni ọ̀rọ̀ náà tó sì tàbùkù òun nítorí ọ̀rọ̀ náà lòdì sí gbogbo nǹkan tí òun gbàgbọ́ nínú rẹ̀.

Ó tẹ̀síwájú pé gẹ́gẹ́ bí ọmọ Yorùbá tí òun jẹ́, èègún ni fún ọmọ láti ṣíwọ́ lu òbí tó bi lọ́mọ àti pé láti bí ogun ọdún sẹ́yìn ni òun ti pàdánù ìyá tó bí òun lọ́mọ.

Ó ní òun kò gbọ́wọ́ sókè lu ìyá òun rí , tí òun kò sì ṣíwọ́ lu ìyá ọkọ òun náà fún gbogbo ìgbà tí òun lò nínú ìgbéyàwó òun.

Ó fi kun pé gbogbo àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ òun ni wọ́n le fìdí àwọn nǹkan tí òun kọ náà múlẹ̀ nítorí kò ṣẹlẹ̀ rárá.

Ta ni Wunmi Toriola?

Wunmi Toriola

Oríṣun àwòrán, Wunmi Toriola/Instagram

Gbajúgbajà òṣèré tíátà Yorùbá ni Wunmi Toriola jẹ́.

Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ogun ni àmọ́ ìpínlẹ̀ Eko ni wọ́n bi sí ní ọjọ́ Kọkànlá oṣù Keje ọdún 1988 sínú ìdílé onígbàgbọ́.

Ìpínlẹ̀ Eko ló ti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti girama kó tó tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Unilorin níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ ẹ̀dá èdè (Linguistics).

Ó darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ eré tíátà Odunfa lábẹ́ àkóso Yinka Quadri, Taiwo Hassan Ogogo, Abbey Lanre, Sunny Alli àti Razak Ajao.

Ní oṣù Karùn-ún ọdún 2018 ni Wunmi Toriola ṣègbéyàwó pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ tó ń gbé ní Amẹ́ríkà.

Ìròyìn ní orí Facebook Wunmi Toriola àti ọkọ rẹ̀ ti pàdé àmọ́ BBC Yorùbá kò le fìdí èyí múlẹ̀.

Ọdún 2019 ni wọ́n bí ọmọkùnrin, Zion èyí Ọlọ́run ti fi ta ìgbéyàwó wọn lọ́rẹ.