Tí àwọn ológun Niger bá kọ̀ láti fi Ààrẹ Bazoum sílẹ̀, a ó lo ọwọ́ líle pẹ̀lú wọn – ECOWAS

ECOWAS

Oríṣun àwòrán, @Dolusegun16

Ajọ ECOWAS ti sọ pe oun yoo ṣeto ikọ ọmọ ogun ti yoo wa ni sẹpẹ lati koju awọn agbesumọ lẹkun iwọ orun Afrika.

Ọrọ yii lo jade lẹyin lẹyin ipade ajọ naa kan to waye niluu Abuja lọjọ Aiku.

Ninu atẹjade kan ti Aarẹ ECOWAS, Omar Touray fi lede lẹyin ipade naa, o ni afojusun ajọ ọhun ni lati ri pe igbesumọmi di ohun igbagbe ni Afrika.

Touray wa ke si awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati forikori lati wa awọn ọna ti igbesunmọmi ko fi ni waye mọ lẹkun ilẹ Afrika.

Iṣẹ ṣi n lọ lọwọ lori ọrọ Niger

Ẹwẹ, alaga awọn Aarẹ orilẹ-ede ECOWAS, Authority of ECOWAS Heads of State and Government, Bola Ahmed Tinubu ti ṣagbekalẹ igbimọ ti yoo tẹsiwaju ijiroro pẹlu awọn ọmọ ogun to ditẹgbajọba lorilẹ-ede Niger Republic.

Awọn Aarẹ naa ni awọn yoo maa dẹwọ awọn ofin to fi de orilẹ-ede naa diẹdiẹ niwọn igba ti ijiroro rẹ atawọn aditẹgbajọba Niger ba n so eso rere.

Wọn ni awọn n fẹ ki awọn ologun naa jọwọ Aarẹ Mohammed Bazoum to wa ni ahamọ wọn, ki wọn si jiroro lori ọna ti ijọba orilẹ-ede ọhun yoo fi pada sọwọ oloṣelu.

Atẹjade naa ni “Inu ajọ yii ko dun bi awọn ologun ṣe n tẹsiwaju lati fi Aarẹ Mohammed Bazoum, awọn ẹbi rẹ atawọn alabaṣiṣẹ rẹ si atimọle.

“Ajọ yii ti pinnu lati gbe igbimọ kan kalẹ ninu eyii ti Aarẹ Togo, Aarẹ Sierra Leaone ati Aarẹ Republic of Benin yoo wa lati maa jiroro pẹlu wọn atawọn mii ti ọrọ naa kan.

“Ajọ yii yoo bẹrẹ si n dẹwo ofin to fi de Niger, amọ o da lori aṣeyọri igbimọ ti a gbe kalẹ.

“Ti awọn aditẹgbajọba naa naa ba kọ lati ṣe awọn ohun ti wọn fẹnuko le lori pẹlu igbimọ ti a gbe kalẹ, a o tẹsiwaju lati maa fofin de ilẹ naa, a ko si ni kọ lati lo ọwọ lile pẹlu wọn.”