Olanrewaju Adepoju fi ewì jà fẹ́tọ̀ọ́ aráàlú, ó tún gbé àṣà Yorùbá lárugẹ – àkọ́bí olóògbé

Aworan Olanrewaju Adepoju

Oríṣun àwòrán, Ayo Ademokoya/Facebook

Ọjọ ti a ba ku laa dere, eniyan o sunwọn laaye.

Ọpọ eeyan ni wọn ti n sọ oriṣiriiṣi ọrọ nipa gbajugbaja Akewi ati olupolongo ẹsin Islaamu nilẹ Yoruba , Oloye Mas’ud Olanrewaju Adepoju to jade laye.

Lẹyin ti o wọ kaa ilẹ sun tan niluu Ibadan lọjọ Aje, akọbi oloogbe naa, Adewale Adepoju sọ fun BBC Yoruba wi pe oloogbe akewi naa ko awọn eeyan mọra.

Adewale ni ”baba mi jẹ baba to fẹran ọmọ, baba daadaa, baba to ko mọlẹbi mọra.

Baba to nifẹ awọn ti wọn n bẹ labẹ wọn, baba ti kii sọ pe ki ẹnikan maa dara.

Baba mi jẹ ajafẹtọ araalu, ti o si korira iyanjẹ ati iwa ibajẹ lawujọ.

Baba mi ko ni kọ lati gbena woju ẹnikẹni, koda ko jẹ oṣiṣẹ ijọba gan an.

-Baba Adepoju maa jẹ ki wọn mọ eyi tii ṣe ododo ọrọ pẹlu ẹbun pataki ti Ọlọrun fi fun wọn nipa ewi kike.

Baba mi jẹ akewi, onkọwe, wọn jẹ akọmọlede, wọn si maa n gbe aṣa larugẹ, wọn si maa n fi ẹwa ede Yoruba han.”

Oloogbe naa tun lo ẹbun rẹ lati ṣe anfani fawọn akẹkọọ.

”Ọpọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ giga ni wọn maa n lo awọn iṣẹ ọwọ Olanrewaju Adepoju lati figba oye kun oye.

Ọrọ pọ ti mo le sọ nipa baba mi, mo kan mẹnu ba diẹ ni.

Baba mi ko faye gba ohun ti ko dara, lojoojumọ ni wọn yoo maa tẹnu mọ ọrọ naa,” akọbi oloogbe ṣalaye.

Aworan oloogbe Adepọju ati awọn ero nibi isinku rẹ

Oríṣun àwòrán, bbc/others

Wọ́n ti sin òkú gbajúmọ̀ akéwì, Olanrewaju Adepoju

Wọn ti ṣeto isinku ogbontagi akewi ati pedepede, Ọlanrewaju Adepọju ni ibamu pẹlu ilana ẹsin musulumi.

Ni ọsan ọjọ Aje ni wọn fi ara rẹ fun erupẹ.

Gbajúgbajà akéwì tó ń fi ewì dárà lédè Yorùbá, Olanrewaju Adepoju jáde láyé

Aworan Lanrewaju Adepoju

Oríṣun àwòrán, Facebook/lanradrecords

Gbajugbaja Akewi ati olupolongo ẹsin Islaamu nilẹ Yoruba , Oloye Mas’ud Olanrewaju Adepoju ti jade laye.

Adepoju to tun jẹ aarẹ Alasa ilẹ Ibadan ki duniya pe o di gbere lọjọ Aiku niluu Ibadan lẹyin to ṣe aarẹ diẹ.

Ọmọ rẹ Adejare Adepoju lo fi ikede iku rẹ soju opo Facebook.

Ẹni ọdun mẹtalelọgọrin ni Olanrewaju Adepoju jẹ ko to jade laye

Lọjọ Aje ni ireti wa wi pe wọn yoo ṣe eto isinku akewi ilumọọka yi ni ilana ẹsin musulumi.

Ọpọ ni yoo ranti Adepoju pẹlu ipa to ko nibi lilo aṣa ati ede Yoruba ni paapa ewi lati fi bẹnu atẹ lu ijọba ologun lorileede Naijiria.

Kikoju ologun nipa lilo ewi yi jẹ ki awọn ologun nigba naa lọhun maa le kaakiri.

Yatọ si pe o jẹ akewi lede Yoruba Adepoju tun jẹ onkọwe.

O kọ iwe kan ti akọle rẹ n jẹ ”Ladepo Ọmọ Adanwo”

Aba Oke Pupa ni ipinlẹ Oyo ni wọn ti bi Olanrewaju Adepoju lọdun 1940.

Gẹgẹ bi akọsilẹ igbe aye rẹ taa ri loju opo poetrytranslation.org,Olanrewaju Adepoju lo kọ ara rẹ lati maa kọ ọrọ lede Gẹẹsi ati Yoruba.

Lati ewe rẹ lo ti sunmọ awọn agbaagba akewi ede Yoruba ti eleyi si mu ki o nifẹ si ede ati aṣa Yoruba.

Adepoju ba wọn ṣiṣẹ nileeṣẹ iwe iroyin ṣaaju ko to di akewi to si gbe iwe ewi kan jade ti akọle rẹ n jẹ Ironu Akewi lọdun 1972.

O tun gbe iwe mii jade ti akọle rẹ n jẹ Ládépò Ọmọ Àdánwò lọdun 1975.

Aworan Olanrewaju Adepoju ati MKO Abiola

Oríṣun àwòrán, lanradrecords

Akewi to ka ijọba ologun laya

Bi a ba ni ka maa ka ni meni meji, ko fẹẹ si akewi ede Yoruba to gbajugbaja to Olanrewaju Adepoju nigba aye rẹ.

Ko si sẹyin bi o ṣe n fi orin ewi rẹ mu iyipada wa lawujọ.

Ni paapa ọpọ lo fẹran ewi rẹ to jẹ bi ibawi ati ipolongo nipa aburu ijọba ologun ni Naijiria.

Ni Naijiria, ati ijọba ologun ati alagbada ko si eleyi to bọ lọwọ ewi Olanrewaju Adepoju ni paapa ijọba to ba n tẹ ẹtọ araalu loju mọlẹ.

Aimọye igba lawọn ijọba ologun fi si atimọle tori pe o fi orin ewi rẹ bawọn wi.

Igboya rẹ yi ati ifẹ to ni si igbelarugẹ aṣa ati ọrọ to ba kan ilẹ Ibadan lo mu ki Olubadan nigba naa lọhun Oba Yusuf Oloyede Asanike fi oye Alasa ilẹ Ibadan da lọla.

Bo ṣe n fi ewi bẹnu atẹ lu awọn ti ko ṣe daada naa si o maa n fi orin ewi rẹ gbe awọn to ba ṣalatilẹyin fun larugẹ.

Oloye Obafemi Awolowo ati MKO Abiola wa lara awọn oloṣelu Yoruba to fi orin ewi rẹ ṣe agbega wọn.

Eyi mu ki awọn ololufẹ rẹ kan yago lẹyin rẹ ṣugbọn ko mu adinku ba ifẹ ti ọpọ ni si akewi yi.

Aworan awo orin Adepoju Ilu le

Oríṣun àwòrán, lanradrecords

Oniwaasu ẹsin Islaamu

Aworan Olanrewaju Adepoju

Oríṣun àwòrán, lanradrecords

Nigbẹhin aye rẹ, ọpọ lo mọ Olanrewaju Adepoju fun ipa toko nidi ipolongo ẹsin Islaamu.

Irinṣẹ ewi rẹ naa lo n ṣamulo lati fi pe awọn eeyan si ẹsin.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí