Moyo Lawal, Mohbad, Peter Obi àti Asake tayọ láàrín àwọn tí aráyé tọpasẹ̀ wọn jùlọ lórí ayélujára lọ́dún 2023

Aworan Moyo Lawal, Mohbad, Murphy Afọlabi ati Asakẹ

Oríṣun àwòrán, Moyo lawal/mohbad/murphy afolabi/others

Ileeṣẹ atọnisọna Google ti kede orukọ awọn eeyan ti araye ṣe ofintoto wọn lori ayelujara julọ laarin ọdun 2023.

Ninu atẹjade kan ti fi sita lọjọ Aje, Google ṣe atupalẹ gbogbo awọn eekan, iṣẹlẹ ati bẹẹbẹ lọ ti araye ṣe ofintito wọn julọ yala lagbo ere idaraya, orin, sinima, iṣẹlẹ gbankọgbi ati bẹẹbẹ lọ.

Moyọ Lawal, ilumọọka elere sinima Yoruba ni ẹni ti araye ṣe ọfintoto nipa rẹ julọ lori ayelujara julọ jakejado orilẹede Naijiria lọdun 2023.

Wyi ko ṣẹyun fidio ihoho Ibalopọ Moyọ Lawal to lu sita si ori ayelujara ni oṣu diẹ sẹyin.

Oludije fun ipo aarẹ Naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu LP ati gbajumọ akọrin, Oladips to parọ iku mọ ara rẹ laipẹ yii lo wa ni ipo keji ati ikẹta ni ṣisẹ n tẹle.

Gbajumọ akọrin takasufe to jade laye ni, Mohbad lawọn eeyan ṣe ofintoto iroyin nipa rẹ julọ lọdun 2023.

Bi ẹ ko ba ni gbagbe, iku Mohbad da ọpọlọpọ ranknkoto ati gbodo n roṣọ silẹ pẹlu bi ọpọ awọn ololufẹ rẹ ṣe woye pe iku rẹ lọwọ ninu.

Bakanna ni gbajumọ aṣebẹgbayi ni, Hilda Bachi pẹlu wa lara awọn ti araalu ṣe ofintoto iroyin nipa rẹwọn julọ lori ayelujara.

Lagbo olorin, Aṣakẹ ni olorin ti awọn eeyan tọ ipasẹ rẹ julọ lori ayelujara ni Naijiria lọdun 2023.

Orin rẹ ‘Lonely at the top’ si ni awo orin ti araalu wa julọ lori ayelujara.

Lara awọn ibeere ti ọpọ beere julọ lori ayelujara ni a ti ri

“ki ni itumọ afikun owo ori epo?” (What is the cause of Mohbad’s death) ati “Ki ni itumọ IDAN?” (What is the meaning of Idan) “Ki ni itumọ ayẹwo fun oku?” (What is autopsy), Iru iku wo lo pa Mohbad (What is the cause of Mohbad’s death) ati bẹẹbẹ lọ.

Awọn eeyan ti awọn eeyan ṣe ofintoto wọn julọ lori ayelujara ni Naijiria lọdun 2023

Moyo Lawal

Oríṣun àwòrán, Moyo lawal/facebook

  • Moyo Lawal
  • Peter Obi
  • Oladips
  • Hilda Baci
  • Mydryk

Awọn iroyin nipa Naijiria ti awọn eeyan ṣe ofintoto wọn julọ lori ayelujara ni Naijiria lọdun 2023

  • Mohbad
  • Nigeria national elections 2023
  • Hilda Baci
  • Mr. Ibu
  • Simon Ekpa
Mohbad

Oríṣun àwòrán, mohbad

Awọn oṣere ti awọn eeyan ṣe ofintoto wọn julọ lori ayelujara ni Naijiria lọdun 2023

  • Moyo Lawal
  • Empress Njamah
  • Mr. Ibu
  • Nancy Isime
  • Yul Edochie

Awọn olorin ti awọn eeyan ṣe ofintoto wọn julọ lori ayelujara ni Naijiria lọdun 2023

  • Asake
  • Khalid
  • Shallipopi
  • Seyi Vibez
  • Kizz Daniel

Awọn orin ti awọn eeyan ṣe ofintoto wọn julọ lori ayelujara ni Naijiria lọdun 2023

Asake

Oríṣun àwòrán, others

  • Lonely at the top – Asake
  • Reason – Omah Lay
  • My G – Kizz Daniel
  • Who is your guy – Spyro ft Tiwa Savage
  • Terminator – KIng Promise

Awọn sinima ti awọn eeyan ṣe ofintoto wọn julọ lori ayelujara ni Naijiria lọdun 2023

  • Gangs of Lagos
  • Jagun Jagun
  • Extraction 2
  • Oppenheimer
  • Barbie movie

Awọn iroyin ọfọ ti awọn eeyan ṣe ofintoto wọn julọ lori ayelujara ni Naijiria lọdun 2023

Murphy Afolabi

Oríṣun àwòrán, murphy afolabi

  • Mohbad
  • Murphy Afolabi
  • Saint Obi
  • Christian Atsu
  • AKA