Tani ‘Tani Ọlọhun’ tó ń dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ fún àwọn Alfaa ìlú Ilorin?

Aworan 'Tani Ọlọhun'

Oríṣun àwòrán, Tani Olohun

Orukọ ‘Tani Ọlọhun’ ti di gbajugbaja ni ipinlẹ Kwara, paapaajulọ ilu Ilọrin bi a ṣe n sọrọ yii.

Fun ign ti olukuluku ba wa ni yoo sọ boya fun rere tabi idakeji rẹ ni orukọ yii n gbajumọ le lori.

Amọṣa, ohun ti ọpọ n beere ni Tani arakunrin yii ati pe kan bawo lo ṣe di ẹni ti gbogbo eeyan n jẹ ọr rẹ lẹnu paapaa bi gbun-gbun-gbun ọrọ ẹsin laarin awọn oniṣẹṣe ati awọn musulumi ni ilu Ilọrin ṣe n fẹju sii.

Ta ni ọkunrin yii ti wọn n pe ni ‘Tani Ọlọhun’

Orukọ abinibi rẹ gangan ni Abdulazeez Adegbọla, ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ si ni.

Gbajumọ ni lara awọn eeyan to n ṣe agbekalẹ lori ayelujara. Ohun to da oun yatọ ni pe iṣẹṣe lo n gbega ninu eto gbogbo to n ṣe lori ayelujara.

Ninu eto rẹ lo ti maa n ṣe alaye nipa igba rẹ ninu ọrọ ẹsin ti o si maa n gbiyanju lati fọnrere iṣọkan lai fi ti ẹsin yoowu ṣe.

Ọpọ awọn eeyan lo n tẹle lori ayeluyara ti wn si maa n fẹ tẹti si i.

Ki lo fa ifanfa laarin oun atawọn ẹlẹsin Musulumi ni Kwara?

Awọn alfaa kan lasiko igbẹjọ naa

Itakangbọn bẹrẹ laarin Ọgbẹni Azeez ‘Tani Ọlọhun’ atawọn aṣiwaju ẹsin Islam ni ilu Ilọrin nigba to bẹrẹ si ni pe ipe fun awọn oniṣẹṣe lati korajọpọ ni ilu Ilọrin fun ayẹyẹ ọdun iṣẹṣe ti ọdun yii.

Ohun ti o n sọ ni pe gẹgẹ bi ọkan lara awọn ilẹ Yoruba, ko si idi fun awọn oniṣẹṣe lati maṣe le e darapọ mọ awọn akẹgbẹ wọn yooku kaakiri ilẹ Yoruba lati ṣami ayajọ ọjọ naa.

Eyi lo bi awọn aṣiwaju ẹsin kan ninu ti ọrọ fi di tasi mi ki n ta si ọ.

Aworan ile ẹjọ lọjọ ti wọn gbe Tani Ọlọhun lọ si ile ẹjọ

Lasiko yii ni wọn sọ wi pe o fi sọ ọrọ alufansa si awọn aṣiwaju ẹsin Musulumi kan nibẹ.

Lara ohun ti wọn sọ pe o sọ ni pe ọpọ awọn alfaa ati imamu gbogbo ni ipinlẹ naa ni wọn maa n ṣe iṣẹṣe ni kọọrọ ati kọlọfin.

Eyi gbodi lara awọn aṣiwaju ẹsin naa ti wọn fi lọ funrawọn gba iwe ifisun ni ile ẹjọ lati pe lẹjọ to fi di ero ahamọ ọgba ẹwọn ni ireti igbẹjọ rẹ loṣu kẹwaa ọdun 2023.