Ṣé lóòtọ́ọ́ ni ìjọba ìpínlẹ̀ Eko dá àwọn olùgbé ìlú Eko kan padà sí ìpínlẹ̀ wọn l’Osun?

Aworan Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X

Iroyin kan to jade lopin ọsẹ to kọja lo sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko pẹlu aṣẹ ijọba fi awọn ọkọ akero ko awọn olugbe ipinlẹ Eko kan pada lọ si ipinlẹ Ọṣun ti i ṣe ipinlẹ abinibi wọn.

Iroyin naa to lu ori ayelujara pa sọ pe ni ṣe lawọn ọlọpaa sa awọn ọdọ kaakiri lawọn oju popo kan niluu Eko ti wọn si fi ọkọ akero nla ko wọn pada si ipinlẹ Osun.

Ileeṣẹ iroyin ori ayelujara kan ni ọkan lara awọn ti wọn ko naa fidi rẹ mulẹ pe nibi iṣẹ loun wa lọjọ Ẹti to kọja tawọn ọlọpaa fi ki oun mọlẹ ti wọn si ni ki oun wọ inu ọkọ akero to n lọ si ipinlẹ Osun.

À wa kò mọ ohunkóhun nípa àwọn ọmọ Nàíjíríà tí wọ́n lé kúrò nílùú Èkó – Ọlọ́pàá

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti pariwo sita pe awọn ko mọ ohunkohun nipa iroyin to lu ori ayelujara nipa dida awọn ọmọ Naijiria kan pada lọ si ipinlẹ Osun lati ilu Eko.

Nigba to n fesi si iroyin ọhun ninu atẹjade to gbe sita, Benjamin Hundeyin to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa jẹ ko di mimọ pe irọ to jinna si otitọ ni iroyin naa.

Hundeyin ko ṣai ṣalaye pe ọlọpaa lọ ko awọn kan ni roga, iyẹn awọn to n rin gberegbere kiri lai ni pato ibi ti wọn n lọ ati awọn to n gbe ibi ti ko yẹ.

Amọ, o ni awọn ko mọ nnkankan nipa bi wọn ṣe ko awọn kan kuro niluu Eko lọ si ipinlẹ Ọṣun, gẹgẹ bi iroyin ṣe kọ ọ.

Aworan Babajide Sanwo-Olu

Oríṣun àwòrán, Screenshot/X

Bakan naa ni Hundeyin fi kun ọrọ rẹ pe bi ileeṣẹ ọlọpaa ba ti mu afurasi, ohun to ṣe pataki si awọn julọ ni lati fi oju iru ẹni bẹẹ ba ile-ẹjọ ki idajọ ododo le waye.

Ninu ọrọ rẹ, o ni “latari iroyin to n lọ kaakiri wi pe ileeṣẹ ọlọpaa…palẹmọ awọn olugbe…lọ si Ọṣun, ileeṣẹ ọlọpaa Eko fẹẹ fi to o yin leti pe wọn ko mọ ohunkohun nipa rẹ, tabi wi pe wọn kopa ninu iṣẹ bẹẹ.

“Ileeṣẹ yii, lojuna lati ṣiṣẹ wọn nipa ṣiṣe awari awọn iwa ọdaran, maa lọ kaakiri lati ṣiṣẹ wọn latigbadegba, ti ọwọ si maa n tẹ awọn kan, ati pe awọn afurasi tọwọ ba ti tẹ maa n foju ba ile-ẹjọ ni lẹyin iwadii.

“Ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Adegoke Fayọade fi n da awọn olugbe ipinlẹ Eko leti pe awọn yoo tubọ maa gbajumọ aabo ẹmi ati dukia araalu ni gbogbo igba.”

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.