Kàyééfì! Furera fi ògùn ẹ̀fọn pa ọmọ orogún rẹ̀, ọmọ ọjọ́ mẹ́rin, lará àdúgbò bá figbe ta!

Aworan

Oríṣun àwòrán, Others

Ọwọ ti tẹ arabinrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Furera Abubakar lori ẹsun pe o pa ọmọ iyaale rẹ, ọmọ ọjọ mẹrin.

Iwadii fihan pe ẹni ti wọn fi ẹsun kan pe o pa ọmọ naa jẹ iyawo keji si iya ọmọ naa.

Ohun ti a gbọ ni pe, ọjọ Karundinlogun, Osu Kẹjọ, ọdun 2023 ni wọn bi ọmọde jojolo naa kí orogun iya rẹ to rọ ọ ni ogun ẹfọn ni ọjọ Kọkandinlogun, Osu Kẹjọ, ọdun 2023 lai jẹ ki ọmọ ọhun duro gba orukọ laye.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe waye?

Iṣẹlẹ naa lo waye ni ilu Bantu, ni ijọba ibilẹ Ningi, ni ipinlẹ Bauchi

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Bauchi, Ahmed Wakil lo fi iroyin naa lede ni ilu Bauchi

‘’Afẹsunkan naa ni o wọ yara iyaale rẹ pẹlu oogun apa kokoro to si fi si okun olubi ọmọ naa ti ko i tii san.’’

Ileeṣẹ ọlọpaa ni ẹni ti wọn fi ẹsun kan naa yoo fi oju wina ofin lẹyin ti iwadii ba pari.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe nṣe ni arabinrin Furera yọ kẹlẹ wọ inu yara orogun rẹ nibẹ lo si ti da ogun ẹfọn si iwọ ọmọ naa ti ko tii jinna.

Ẹni ọdun mẹrinlelogun ni Furera Abubakar.