Wo bí àṣírí ọ̀gá bánkì tó rí ẹ̀wọn ọdún mọ́kànlélọ́gọ́fà he lórí ẹ̀sùn jìbìtì N112m ṣe tú

Aworan Nwachukwu Placidus

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook

Ile-ẹjọ giga ti ipinlẹ Anambra ti ju ọga agba tẹlẹ nile ifowopamọ First City Monument Bank, FCMB, ẹka tiluu Onitsha, ipinlẹ Anambra, Nwachukwu Placidus sẹwọn ọdun mọkanlelọgọfa (121years) lori ẹsun jibiti.

Adajọ S. N. Odili gbe idajọ naa kalẹ lẹyin to ni awọn ẹri toun ri gba lori ẹsun ti wọn fi kan Placidus kọja ohun ti wọn le dawọ bo mọlẹ.

Owo to le diẹ ni miliọnu mejilelaadọfa (N112,100,000) naira ti wọn ko pamọ si banki ti Placidus ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bi alakoso ni wọn lo jigbe, to si sọ ọ di ti ara rẹ.

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission ni wọn mu Placidus lọdun 2018, ti wọn si foju rẹ ba ile-ẹjọ fun igba akọkọ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2018.

Lara awọn ẹsun mẹrindinlogun ti wọn fi kan Placidus ni yiye iwe, jija ole, ilọnilọwọgba ati pinpin owo olowo kaakiri, ati awọn miran.

Aarin ọdun 2009 si ọdun 2014 ni ajọ EFCC ṣalaye pe Placidus lu jibiti ọhun, ko to di pe aṣiri rẹ tu sita, ti ọwọ palaba rẹ si segi.

EFCC sọ pe Placidus, nigba ti wọn kọkọ foju rẹ ile-ẹjọ sọ pe oun ko jẹbi pẹlu alaye, ṣugbọn ti agbẹjọro awọn, Mainforce Adaka Ekwu pe ẹlẹri mẹrin ọtọọtọ lati wa jẹri.

Ẹlẹri mẹrẹẹrin ni ajọ EFCC sọ pe wọn mu awọn iwe ẹri loriṣiriṣi kalẹ, eyi to fi han pe wọn ko purọ mọ ọn.

Ninu idajọ Onidajọ Odili, o ni ki Placidus lọ ṣẹwọn ọdun mẹsan lori ẹsun kẹta; ẹwọn ọdun mẹrin lori ẹsun kẹrin, ati ẹwọn ọdun mẹsan lori ẹsun karun-un titi de ikẹrindinlogun.

Bi aṣiri ṣe tu ree

Ile ifọwopamọ ti ẹyawo kan ti wọn pe ni Idemili Microfinance Bank LTD, ni wọn mu ẹsun lọ sọdọ ajọ EFCC wi pe awọn ko miliọnu mejilelaadọfa le lẹgbẹrun lọna ọgọrun (N112, 100, 000) naira fun Placidus lati ba wọn fi pamọ.

Wọn lawọn ko ṣiye meji lori Placidus nitori pe oun ni alakoso ile ifowopamọ ọhun, idi ree ti wọn ko owo naa fun un lati ba wọn tọju, ki ele le maa wa lori ẹ ni gbogbo igba, eyi ti wọn n pe ni ‘Fix Deposit’.

EFCC sọ pe nigba ti banki ọhun lọ lati gba owo wọn pada, iyalẹnu nigba ti wọn sọ pe banki FCMB sọ pe awọn ko gba owo to to bẹẹ wọle rara.

Eyi lo mu ki awọn alakoso banki ẹyawo naa gba ọdọ ajọ EFCC lọ lati fi to wọn leti, ti wọn si ṣe iwadii, ko to di pe aṣiri pada tu sita pe Placidus ko ko owo kankan pamọ si banki to ti n ṣiṣẹ.