Akẹ́kọ̀ọ́ Kwara méjì fakọyọ nínú ìdánwò JAMB, gba máàkì 358 àti 362

Kwara

Oríṣun àwòrán, KSG

Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ ìjọba ní kwara ṣe bẹbẹ nínú èsì ìdánwò jamb, gẹ́gẹ́ bó ṣe gba 358 nínú ìdánwò.

Akekọọ ile ẹkọ girama ipinlẹ Kwara wa lara awọn akẹkọọ to fakọyọ julọ ninu idanwo JAMB ọdun 2024.

Akẹkọọ naa ti orukọ rẹ n jẹ Samuel Olanrewaju Semilore lo jẹ akekọọ ile ẹkọ girama Government Secondary School, to wa niluu Omu-Aran ni ijọba ibilẹ Irepodun

Semilore gba maaki 358 ninu idanwo JAMB tọdun yii to jade lọṣe to kọja.

Lasiko to n ba akọroyin BBC sọrọ, Semilore sọ pe inu oun dun pupọ lori esi idanwo ọhun.

Ninu ọrọ iya akẹkọọ naa, o dupẹ Ọlọrun fun aṣeyọri ọmọ rẹ.

Giwa ile ẹkọ naa, Ajewole Olusola ṣalaye pe aṣeyọri ọmọ naa ko ba ohun lojiji nitori o ma n ṣe daadaa ninu idanwo ile ẹkọ awọn ṣaaju idanwo JAMB.

Ọmọ ọdun marundinlogun ni Semilore lati ilu Omu-Aran, ni ijọba ibilẹ Irepodun.

Ẹwẹ, Victor Olukayode ti ile ẹkọ girama aladani His Grace College Ilọrin ṣe daadaa ninu idanwọ JAMB ọhun.

Olukọ to n kọ Olukayode ni imọ Geography, Isayọmi Adekunle juwe akekọọ naa bii ẹni to farabalẹ ni yara ikekọọ.

Ninu ọrọ iya rẹ, Arabirin Olusola Iranloye, o ni inu oun dun pupọ fun aṣeyọri ọmọ oun.

Victor Olukayọde Olusọla gba makii 362, ti atupalẹ rẹ jẹ;

  • Eng 77
  • Maths 95
  • Physics 95
  • Chemistry 95