Afurasí ìbejì tó n jalè dèrò àtìmọ́lé l’Ekiti

Awon ibeji

Oríṣun àwòrán, Ekiti Police

Ọrọ Yoruba kan to sọ pe ọmọ iya meji kii rewele ko ṣiṣẹ rara fun awọn ibeji wọnyi ti wọn sọ pe wọn fẹran lati ja ilẹkun ile onile ati ṣọọbu lati jale nibẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti lo kede sita laipẹ yii wi pe ọwọ awọn tẹ ibeji ti wọn pe orukọ wọn ni Taiwo ati Kẹhinde Ọlasọji pẹlu awọn meji miran, Funkẹ Afọlayan ati Nnaji Aroh lori ẹsun ole jija.

Ninu atẹjade ti ọga ọlọpaa Ekiti, Adeniran Akinwale gbe jade, eyi ti Sunday Abutu to jẹ agbẹnusọ buwọ lu laipẹ yii lo ti jẹ ko di mimọ pe ilu Ado-Ekiti lọwọ ti tẹ awọn mẹrẹẹrin.

Akinwale ṣalaye pe ọjọ karundinlọgbọn, oṣu kẹrin ti a wa yii lọwọ palaba awọn ibeji naa segi lasiko ti wọn n gbiyanju lati ja ṣọọbu itaja kan ladugbo Mathew to wa ni Odo-Ado, Ado-Ekiti.

Ninu ọrọ rẹ, o tẹsiwaju pe awọn ibeji naa ti jẹwọ, ati pe bi wọn ṣe jẹwọ lo mu ki ọwọ tẹ Funkẹ ati Nnaji ti awọn maa n gba ẹru ti wọn ba jigbe lọwọ wọn.

O ni awọn ibeji naa ṣalaye pe awọn ni wọn lọ fọ ṣọọbu mẹta ọtọọtọ to wa ninu ọja Fayẹmi, Agric Ọlọpẹ to wa nilu Ado-Ekiti, ti wọn si ji apo irẹsi mẹta, apo ẹwa meji ati awọn ohun jijẹ miran ti owo wọn din diẹ ni miliọnu kan (N936,750) naira.

Akinwale ti wa fidi rẹ mulẹ pe gbogbo wọn ni yoo foju ba ile-ẹjọ lati sọ tẹnu wọn.