Kí ni pàtàkì ìdásílẹ̀ àjọ àwọn orìlẹ̀èdè BRICS tó ń pàdé ní South Africa báyìí?

BRICS

Oríṣun àwòrán, getty images

Awọn adari ajọ BRICS lagbaye, Brazil, Russia, India, China ati South Africa ni ipade wọn yoo waye ni ọjọ Kejilelogun, Osu Kẹjọ, ọdun 2023 ni ilu Johannesburg, ni orilẹede South-Africa.

Lara awọn ohun ti wọn yoo maa jiroro le lori ni bi wọn yoo se gba awọn miran laaye sinu ajọ naa.

Ijọba orilẹede South Africa to n gbalejo ni o kere tan ogoji orilẹede ni o ti ṣetan lati darapọ mọ wọn bayii.

Bawo ni wọn ṣe da Ajọ BRICS silẹ?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ni ọdun 2001 ni onimọ nipa eto ọrọ aje, Jim Ońeil da asopọ ọrọ BRIC kalẹ fun Brazil, Russia, India ati China.

Awọn orilẹede yii ni wọn ni eto ọrọ aje to n dagba soke si, to si ṣeeṣe ki wọn goke agba ni ọdun 2050.

Ni ọdun 2006, awọn orilẹede mẹrin naa lo jumọ pọ lati da ajọ naa silẹ, ti South Africa si darapọ mọ wọn ni ọdun 2010.

Kini pataki ajọ Brics yii?

Ni apapọ awọn araalu awọn orilẹede ni owo ti iye rẹ ju biliọnu mẹta lọ pẹlu apapọ iye owo to n wọle ni abele to to $26 tiriliọnu.

Amọ iwadii ti ileeṣẹ Atlantic Council gbe jade ni BRICS ni ida marundinlogun aṣẹ lati buwọlu eto isuna ni agbaye ni ajọ United Nations, ati International Monetary Fund, IMF.

Aworan awọn orilẹede to wa labẹ ajọ Brics

Kini erongba ajọ BRICS?

Ajọ naa ni wọn gbekalẹ lati wa ọna bii awọn orilẹede ti ọrọ aje wọn ṣẹṣẹ n gbera ṣe le ni ẹnu ọrọ ninu ajọ IMF ati Banki Agbaye, World Bank.

Ni ọdun 2014 ni ajọ BRICS da banki New Development Bank silẹ lati maa ya awọn orilẹede ti ọrọ aje wọn ṣẹṣẹ n gbera soke ni owo.

Njẹ ajọ BRICS yoo ni owo idanimọ ẹyọkan

Orilẹede Brazil ati Russia to n saju ninu ajọ naa ti fi aba lede lati gbe igbesẹ nipa nini owo kan naa.

Eyi yoo figagbaga pẹlu owo dọla to gba eto ọrọ aje kan.

Amọ aṣoju orilẹede South Africa ati Russia, Anil Sooklal ni awọn ko ni gbe yẹwo nibi ipade naa ti yoo waye.

Kini o wọpọ laarin awọn ọmọ ajọ naa?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bo tilẹ jẹpe awọn orilẹede to wa ni abẹ ajọ naa ni wọn n dagba ni eto ọrọ aje wọn, amọ orilẹede China ni oun lewaju ninu wọn

Awọn to wa ninu ajọ naa n gbaradi lati koju bii orilẹede Amerika se fẹ dari eto ọrọ ajẹ ni awọn agbegbe yii.

Wọn tun ṣe atilẹyin fun China fun idagbasoke rẹ ni agbegbe naa.

Amọ ajọ BRICS naa ko fi imọ ṣe ọkan lori iha ti wọn kọ si awọn orilẹede ni iha iwọ oorun lagbaye.

Awọn orilẹede wo lo fẹ darapọ mọ BRICS?

Aṣoju orilẹede South Africa ati Asia, Anil Sooklal ni orilẹede 22 lo fẹ darapọ mọ wọn.

Iran, Argentina, Cuba, Kazakhstan, Ethiopia, Saudi Arabia, United Arab Emirates ati Venezuela.

Awọn onimọ ti sapejuwe igbese naa gẹgẹ bi eyi ti yoo lera diẹ nitori awọn orilẹede to wa nibẹ.

Amọ wọn ni awọn orilẹede to Argentina ti wọn yatọ si orilẹede bii Iran ni yoo ni anfaani lati wole.

Kini wọn yoo jiroro lori nibi ipade naa ni South Africa?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọjọ Kejilelogun si ikẹrinlelogun, Osu Kẹjọ, ọdun 2023 ni ipade naa yoo waye ni Johannesburg.

Lara awọn ohun ti wọn yoo jiroro le lori ni ọna ati gba awọn to fẹ darapọ mọ wọ wọlẹ.

Nkan miran ti wọn yoo jiroro le lori ni ọrọ oju ọjọ, idokowo, ọna idagbasoke ọrọ aje lagbaye, to fi mọ eto oṣelu ni agbaye.

Orilẹede South Africa ti fi iwe pe awọn ọrilẹede bii ọgọta lati ilẹ Africa, Latin America, Asia ati Caribbean lati darapọ mọ wọn.

Amọ aarẹ orilẹede Russia ko ni yọju sibẹ nitori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an lori ogun to n lọ lọwọ laarin Russia ati Ukraine,to si ni oun ko jẹbi ẹsun kankan.