Ọmọọba Harry àti Meghan Markle fẹ́ ṣàbẹ̀wò sí Naijiria l’oṣu karun-un

Aworan Prince Harry ati Meghan Markle

Oríṣun àwòrán, Nigeria Defense

Gbogbo eto lo ti fẹẹ pari bayii fun Ọmọọba ilẹ England, Ọmọọba Harry ati iyawo rẹ, Meghan Markle lati ṣabẹwo si orileede Naijiria.

Abẹwo ọhun la gbọ pe o lọ nibamu pẹlu ere idaraya kan ti wọn pe ni Invictus Games, eyi ti wọn bẹrẹ fun igba akọkọ lọdun 2014.

Invictus Games ni idije ere idaraya ti wọn ṣagbekalẹ rẹ fawọn oṣiṣẹ ologun ati agbofinro ti wọn farapa loju ogun, lati maa fi dun wọn ninu.

Inu oṣu karun, ọdun 2024 ti a wa yii ni Ọmọọba Harry ati Meghan Markle yoo de si Naijiria, lẹyin to ba kuro ni United Kingdom ti wọn lọ ṣabẹwo si.

Awọn mejeeji yii ni wọn fẹẹ wa lati sọrọ lori idije Invictus Games naa to fẹẹ waye laipẹ.

Nigba ti wọn ba de si Naijiria, a gbọ pe wọn yoo kopa ninu awọn aṣa ati iṣẹṣe pẹlu awọn oṣiṣẹ ologun ati agbofinro to fi mọ awọn mọlẹbi wọn.

Abẹwo yii si ni yoo jẹ igba akọkọ ti tọkọ-taya naa yoo maa ṣabẹwo silẹ Afrika gẹgẹ bii tọkọ-taya, to si ṣe pataki pupọ ninu ọkan Meghan, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Ninu ọrọ to fi lede ninu fọnran rẹ, Meghan to ti figba kan ri jẹ oṣere ṣalaye pe oun ni orirun lorileede Naijiria.

Bakan naa ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu oṣere ọmọ ilẹ Naijiria ati Amẹrika nni, Ziwe, Mehgan sọ pe ida mẹtalelogoji ara oun lo jẹ ti Naijiria, ati pe oun ṣawari yii lẹyin ayẹwo toun ṣe lọdun diẹ sẹyin.

Meghan ni bo tilẹ jẹ pe oun ko le sọ pato ibi ti awọn baba nla oun ti wa gan-an ni Naijiria, ṣugbọn sibẹ, o jẹ ko di mimọ pe oun yoo ṣe iwadii ijinlẹ lee lori.

Tọkọ-taya yii yoo wa nibi isin idupẹ ti yoo waye nile ijọsin St Paul’s Cathedral lọjọ kẹjọ, oṣu karun-un.

A ṣetan lati daabo bo Ọmọọba Harry ati Meghan Markle – Ileeṣẹ alaabo Naijiria

Ileeṣẹ eleto aabo ilẹ Naijiria, Nigeria Defence ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti ṣetan lati daabo bo Ọmọọba Harry ati aya rẹ, Meghan Markle ni gbogbo asiko ti wọn yoo lo lorileede naa.

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ yii lo fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade ti wọn gbe soju opo ikanni ayelujara ti ‘X’ wọn lọsan oni (Monday).

Nibẹ ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn naa wa lara awọn to n kopa ninu idije Invictus Games ọhun, ti wọn si lo di dandan lati daabo bo awọn oludasilẹ idijẹ ọhun.

Skip Twitter post

Allow Twitter content?

This article contains content provided by Twitter. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Twitter cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Twitter post

Content is not available

View content on TwitterBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.