‘Tani Olohun’ dèrò àhámọ́ fún ọjọ́ 50 fún ẹ̀sùn bíba àwọn Alfa kan lórúkọ jẹ́ nílùú Ilorin

Ile ẹjọ Ilorin

Ile-Ejọ Majisireti kan ti o kalẹ si Ilọrin, olu ilu ipinlẹ Kwara kun fọfọ ni ọjọ Ọjọbọ osu ogun odun 2023, latari igbẹjọ okunrin kan ti nse, Adegbọla Abdulazeez ti inagi re njẹ Talọlọrun.

Talọlọrun ni wọn pe lẹjọ fun ẹsun igbimopọ, itabuku, biba ẹsin jẹ, ibanilorukọ jẹ ati dida rogbodiyan silẹ, eyi ti o lodi si abala ofin 97, 210, 392, ati 114.

Adajọ fun igbẹjọ naa, Majisireti Muhammed Ibrahim kede atimọle aadọta ọjọ (50) fun un ki igbẹjọ to tẹsiwaju ni ọjọ kaarun osu kẹẹwa ọdun 2023.

Ṣe ni awon ọdọ musulumi lọkunrin ati lobirin tu si ita ti won n kọrin wipe “Talọlọrun wọlẹ lọ bi awada bi ere”.

Ati orin bii, “gbogbo ọta Ilọrin ki won maa lọ si Okekura” (iyẹn ọgba ẹwon ilu Ilorin).

Awọn ara Ilorin

Ẹsẹ wo gan ni Talọlọrun ṣẹ?

Agbẹjọro

Gẹgẹ bi iwe ẹsun awon ọlọpaa ti sọ, Talọlọrun gbimo pọ pẹlu awon kan ti ọwọ ko tii tẹ lati ba ẹsin Islam jẹ, wọn sun Kurani ni ina won si tun ba awon ọjọgbọn Alfa kan ni Ilọrin lorukọ jẹ.

Iwe naa tun fi idi rẹ mulẹ pe Talọlọrun tabuku Imamu Agba ti ilu Ọffa, Alhaji Muuhideen Salman Hussein, Alfa Ahmad Labeeb Agbaji, Alfa Abdulsalam Baba-Tonile, ati Okuta-Agidi, o si sọ wi pe oloogbe Okgbuta-Agidi ti o jẹ baba Olorisa, Alfa eke ti o si ni ojubọ ni ile ti oun bọ ni igba aye rẹ.

Won tun sọ pe Talọlọrun dunkoko lati da ogun silẹ ni Ilọrin ati agbegbe rẹ nipa kikọ, ati sisọ oniruuru ọrọ lori itakun ayelujara rẹ.

O tun fi atẹsita pe awon onisẹse lati pade ni Ilọrin ni ogunjọ osu yii.

Awọn ara Ilorin
Alfa agba kan ni Ilorin

Agbẹjọrọ fun ọlọpaa, Yusuf Nasir gba ile ẹjọ ni iyanju lati fi Talọlọrun si ahamo idi si ni wipe fun idaabobo ẹmi rẹ.

Agbejọro fun Talọlọrun, Muftau Olobi Olufọda sọ fun ile ẹjọ lati lo oye rẹ nipa ọrọ naa bo tilẹ jẹ wi pe ẹsun ti won fi kan onibara rẹ jẹ eyi ti ile ẹjọ le fi silẹ titi di igbẹjọ miran.

Ninu ọrọ rẹ leyin idajọ naa Hussein Fọlọrusọ Faagba ti o duro fun ẹgbẹ ọmọ Ilọrin lokunrin ati lobirin ti wọn fi igbẹjọ lede si Kọmisọna Ọlọpaa ti Kwara sọ pe ile ẹjọ ti pa laṣẹ ki enikẹni ma ṣe tapa si ofin titi di ọjọ igbẹjọ to n bọ.

Majisireti Ibrahim ninu idajọ rẹ, paa la ṣẹ pe ki won fi Talọlọrun si ahamo ile ẹwọn ijoba apapọ, Mandala titi di ọjọ karun-un oṣu kẹwa ọdun 2023.

Awọn ara Ilorin