NÍ YÀJÓYÀJÓ Ẹ̀gbọ́n mí kú fún ìrètí gbogbo wa

Copyright: MAMOUR BA

Aburo ọkan lara awọn eeyan to padanu ẹmi rẹ ninu Ijamba ọkọ oju omi to waye lorilẹede Cape Verde sọ fun BBC pe o un gbinyanju lati de si orilẹede Spain.

O to ọgọta eeyan to ku ninu ijamba ọkọ oju omi, to ti wa lori fun oṣu kan. Pupọ awọn eeyan lo wa lati orilẹede Senegal.
“Gbogbo wa lo yalẹnu. Ọkan lara opo idile wa ni,”

Mamour Ba sọrọ nipa ẹgbọn rẹ Cheikhouna.
Sugbọn, Ba, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni oun yoo si tun gbinyanju lati kuro lorilẹede Senegal nitori o nira lati se orire lorilẹede Senegal to wa.

Mẹta ninu awọn ọmọ iya rẹ ọkunrin ati ọmọ ẹgbọn baba rẹ lo kan agbako iku ojiji ninu ijamba ọkọ oju omi oni pako to gbera lati abule Fass Boye pẹlu eeyan kan le ni ọgọrun un lọ si ilẹ Europe.

“Wọn fẹ lọ si orilẹede Spain. Wọn sọ fun mi pe awọn fẹ lọ, n ko si le sọ fun pe ki wọn ma lọ nitori wọn ti ipinnu lọkan wọn.

O ro pe gbogbo wọn ti ku, ko to wa gba ipe lati Cape Verde lọjọru pe wọn ri awọn kan dola.
Wọn wa lara eeyan mejidinlogoji, pẹlu ọmọde ti yi yọ sita ninu omi
Ba ni oun ko ti le sọ nipa ilera awọn mọlẹbi rẹ,

“Wọn ko ni okun lati salaye nnkan to sẹlẹ , wọn kan ni awọn wa laaye.


Sugbọn ifọrọwerọ naa fihan pe ki se gbogbo wọn lo moriyọ ninu ijamba naa laye.

“Ọkan lara awọn ẹgbọn mi, Ibrahima fi foonu dokita pe mi lati Cape Verde.

“O sọ fun wa wipe Cheikhouna sọnu ninu omi. Mo ba mi lọkan jẹ. A sumọ ara wa gan, jagunjagun ni.

O ti ni iyawo pẹlu ọmọ meji.
“Ijo to kuro ni ile, o di ọwọ mi mejeeji mu, O ni Aburo mi, mo ni lati lọ.
“Ẹgbọn mi, ọrẹ mi si tun ni.”