Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa owó $3 bilion tí iléṣẹ́ ìpọnpo NNPCL yá lórí ọ̀rọ̀ epo

Aworan Asia NNPC

Oríṣun àwòrán, nnpc

Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ, Ileeṣẹ ipọnpo orilẹede Naijiria (NNPC) kede awọn ti ya owo pajawiri biliọnu mẹta Dollar latọdọ Banki to n ri si iwọle-wọde ọja l’Afirika (AFREXIM).

Ninu atẹjade kan ti ajọ NNPC fi soju opo Twitter, ileeṣẹ naa ni iwe adehun naa ni awọn tọwọ bọ ni olu ileeṣẹ banki AFREXIM to wa ni Cairo lorilẹede Egypt ni Ọjọru ọsẹ.

Atẹjade naa ṣalaye pe adehun yii yoo jẹ ki wọn le ṣeranwọ fun ijọba apapọ Naijiria ninu akitiyan to n ṣe lọwọ fun atunto ẹka inawo ati lati fopin si ṣegeṣege ti pasiparọ owo ilẹ okere n ṣe

Oludamọran fun Aarẹ Bola Tinubu, O’tega Ogra salaye lori ayelujara ohun owo ọhun wa fun ati igbesẹ ti ijọba fẹ gbe lati lo owo naa si bi to tọ.

Ninu alaye rẹ, o ni ọhun yoo pese iranwọ kiakia ti yoo le jẹ ki ileeṣẹ NNPC nawọ iranwọ si ijọba apapọ ninu akitiyan rẹ to n lọ lọwọ fun atunto ẹka inawo ati ki iduro dede le wa fun pasiparọ owo ilẹ okere.

O tẹsiwaju pe ọkan lara anfani ti yoo tun se fun ijọba apapọ ni pe yoo fun owo naira ni aponle lawujọ,

Ogra salaye kikun bi anfani owooya si ijọba apapọ ati orilẹede Naijiria.

Sugbọn pupọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo tako igbesẹ, ti wọn kegbe bọ ẹnu pe ko ki se isẹ ileeṣẹ NNPC lati yawo fun ijọba.

Ki ni Bilọnu mẹta dọla ti wọn ya naa wa fun?

ileeṣẹ NNPCL ya owo pajawiri bilọnu mẹta owo dola ilu rọbi lati ọwọ ajọ ileeṣẹ banki AFREXIM kan lati san gbese to wa nilẹ.

E yi ki se eto ẹyawo onipaṣiparọ epo rọbi tutu fun epo ti wọn ti fọ.

owo naa wa lati sanowo asansilẹ lori awọn ohun ti wọn n ri lara ipọnpo rọbi

Ki ni anfani owooya yii fun Naijiria?

Owooya yii yoo se iranlọwọ fun ileeṣẹ iponpo NNPCL lati san asansilẹ owo ori. Bakan naa ni yoo ṣe iranlọwọ ijọba apapọ tani isoro bi owo Naira ko se ba ẹgbẹ pe.

Bawo ni wọn se fẹ na owo yii?

Onipele ni nina owo naa gbajade pẹlu ilana ti ijọba apapọ ba gbe kalẹ

Se yoo ni ipa lori iye owo ti araalu n ra epo?

Bi owo Naira ba ti ba ẹgbẹ pe, ẹyi to jẹ idi ti wọn fi gbe igbesẹ yii, owo epo yoo walẹ. Eyi tumọ si pe ti igbega ba de ba owo Naira, iye owo epo yoo walẹ, ti yoo si lọ soke to ba tun fidi rẹmi

Se kii se ọna ero niyi lati da owo iranwọ ori epo pada?

Rara o. Agbega owo naira tumọsi pe ọwọn gogo gbogbo nnkan yoo walẹ. Ijọba ko yi ipinnu wọn pada.

Bawo ni gbese yii yoo se di sisan pada?

Owooya yii ni yoo di sisan lati gbedi dina iyakuro ni pipese epo rọbi. Igbesẹ yii ni yoo ri daju pe agbega ba eto aje ati pipese epo lọjọ iwaju.

Ki ni iyatọ laarin ti talẹyinwa ati eyi?

Owooya yii ko wa fun ṣiṣe atunse epo rọbi ti ijọba ko ni ri ere ni bẹ.

Aworan ileepo NNPC

Oríṣun àwòrán, NNPC

Isẹ wọn kọ ni wọn se- Ọjọgbọn Awosika

Ileeṣẹ BBC ba Ọjọgbọn Abiola Awosika salaye pe ohun iyalẹnu lo jẹ pe Ileeṣẹ NNPCL lọ ya owo lati se iranlọwọ fun owo Naira.

Awosika ni nnkan ti ileeṣẹ NNPCL n gbero lati fi owo se tabi idi ti wọn fi lọ yawo ko si ni ilana isẹ wọn

“Wọn ni awọn yawo lati jẹ ki owo wa ni agbara si, n ko ro pe isẹ wọn ni nitori wọn gba isẹ oni isẹ se ni

“Ti wọn ni owo ti wọn lọ ya ma jẹ ki owo epo bentiro dikun, mo gba

“Ti wọn ba ya owo, ti wọn fi se nnkan to yẹ ki wọn na ki epo walẹ, nnkan to da ni”

Ijoba Tinubu ti fẹ bẹrẹ nnkan ti ijọba n se- Agbẹjọro

Agbẹjọrọ Adebisi Iyaniwura ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu ileeṣẹ BBC ni o se ni laanu pe ijọba Bola Tinubu ti fẹ rawọ le nnkna ti ijọba ana ti Muhammadu Buhari junle.

O bu ẹnu atẹlu ọna ti ileeṣẹ NNPCL gba lati ya owo ati idi ti wọn fi yawo ọhun.

“Ijọba sọ pe awọn ti sọ NNPCL di ileeṣẹ aladani, bawo wa ni ileeṣẹ aladani ma se lọ yawo lokere fun ijọba apapọ?

“Ofin ni ileeṣẹ aladani ko gbọdọ ya owo ayafi owo to fẹ lo fun ara rẹ nikan, to si yawo to jere, ere naa naa awọn to n se onigbọwọ, ti Naijiria jẹ ọkan yoo pin.

“Ibo ni wọn ti n se iyẹn pe awọn ran ijọba lọwọ”

“Yiyawo lati okere ko bu ọla fun Banki apapọ wa”

Iyaniwura tẹsiwaju pe o ku diẹ kato fun ileeṣẹ NNPCL lati ni awọn lọ ya lati okere nigba ti banki apapọ wa ni arawọto wọn.

“Ileeṣẹ NNPCL ja banki apapọ wa ni irawọ, boyo nitori wọn ko fọkan tọ Banki apapọ lati ba wọn dowopọ, lati ma ya awọn lowo.

“Owo ti ileeṣẹ NNPCL ya yii ko ni wa lara gbese ti ijọba jẹ sugbọn orukọ ijọba ni wọn fi ya owo naa

“A ti n pada lọ si ẹsẹ arọ wa niyi.”