Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ obìnrin tó jí ara rẹ̀ gbé, bèrè ₦4m owó ìtúsílẹ̀

Nigeria Police

Oríṣun àwòrán, getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ti fi ṣikun ofin mu obinrin kan to ji ara gbe, to si bere owo itusilẹ miliọnu mẹrin naira fun irusilẹ ara rẹ.

Yatọ si obinrin ọhun, ileeṣẹ naa tun fi ṣikun ofin mu awọn afurasi mejilaadọta miran, wọn tun doola eeyan mẹrin to ko sọwọ awọn ajinigbe laarin oṣu kan sẹyin.

Kọmiṣona ọlọpaa ipinlẹ ọhun Waheed Ayilara lo fi ọrọ naa to awọn akọroyin leti niluu Uyo lọjọ Ẹti.

O ni lara awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn afurasi mejilelaadọta yoku ni ipaniyan, ijinigbe, idigunjale, fifi ọmọde ṣowo ti ko tọ, ṣiṣe ẹgbẹ okunkun ati lilu jibiti.

Ayilara sọ pe ọkan lara awọn ti wọn jigbe ni ijọba ibilẹ Ibesikpo Asutan lo ṣamọna bi wọn ṣe jii gbe funra rẹ.

Lẹyin ti wọn ji gbe tan lo tun bere fun miliọnu mẹrin naira owo itusilẹ.

O ni “Obinrin kan, Enobong Sampson wa sọ ni agọ wa pe wọn ji ẹgbọn oun obinrin gbe ati pe awọn ajinigbe naa n bere miliọnu mẹrin naira.

“Idi ree ti awọn akọṣẹmọṣẹ ikọ Anti-kidnapping Squad wa ṣe bẹrẹ si n wa awọn ajinigbe naa lati doola rẹ.

“Amọ lọjọ Iṣẹgun, ọwọ wa tẹ ẹni ti wọn ji gbe naa ati ọrẹkunrin rẹ nibi ti wọn lugọ ni Mbierebe Obio, to wa ni ijọba ibilẹ Ibesikpo Asutan.

“O jẹwọ pe oun loun gbimọ pọ pẹlu ọrẹkunrin oun atawọn mẹta mii lati sọ fun awọn mọlẹbi rẹ pe wọn ji oun gbe lọna ati kowojọ lati japa lọ soke okun.”

Ayilkara fi kun pe ọwọ awọn tun tẹ ọkunrin kan to n ṣe ayedru ẹlẹrindodo.

O pari ọrọ rẹ pe awọn afurasi naa yoo foju bale ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari lori ọrọ wọn.