Elédùwà fi ìbejì ọkùnrin àti obìnrin kan dá Ooni Ile Ife àti Olorì Tobiloba lọ́lá

Aworan Ooni ati Olori Tobiloba

Oríṣun àwòrán, Ooniadimulaife/Instagram

Ayọ abara tintin, Olodumare ti fi ibeji ọkunrin kan ati obinrin kan ta Ooni Ile Ife, Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja Keji ati Olori Tobiloba lọọrẹ.

Kabiyesi Ogunwusi gan-an gan-an lo kede iroyin ayọ yii loju opo Instagram rẹ lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹta yii.

Kabiyesi sọ loju opo Instagram rẹ pe lọjọ Satide yii naa ni Olori Tobiloba bi awọn ori-ade yii.

‘’Ogo ni fun Eleduwa loke ọrun nitori O ti ṣe ohun nla.

Ẹ ku oriire o gbogbo idile Oduduwa pẹlu bi Olori Tobiloba ti bi Ọmọbakunrin kan ati Ọmọbabinrin kan.

Awọn ori-ade yii ni Eleduwa ṣẹṣẹ ṣe afikun wọn si ori itẹ Oduduwa.

A dupẹ lọwọ Ọlọrun pe iya ikoko atawọn ọmọ mejeeji lo wa ni alaafia,’’ Ooni lo sọ bẹẹ.

Ẹwẹ, ọpọ ololufe Kabiyesi ni wọn ti n ki Ooni ati Olori Tobiloba ke ewu ọmọ.

Chessy.man ni tiẹ sọ pe ‘’Kabiyesi oo Arole Oodua. Ẹ ku oriire o, jingbinni bi ate akun.

Oluwa a da awon omo naa si oooo.’’

Nikky_babe17 ni ‘’A ku ewu Omo naaa, Olorun a kawon Kun wa. Ase waaaaa.’’

Ashabi¬_olorisha ki Kabiyesi bayii ‘’wahoo ooo! IBEJI ni oo!

Ọmọbakinrin ati Ọmọbabinrin nio, Ẹ ṣe o, OLODU-TO-MA’RE, OLUWA OLORUN OBA.

Ẹ ku oriire, ADIMULA ERU JEJE

Baba Alariya ni tiẹ sọ pe, ‘’ẹ ku oriire, Baami Arole Oodua!’’

Ọpọ eeyan ti a ko le darukọ wọn tan lo ki Kabiyesi ati Olori Tobiloba ku ewu loju opo ayelujara Instagram rẹ.

Skip Instagram post

Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose ‘accept and continue’.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Content is not available

View content on InstagramBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.