Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ èèyàn mẹ́rin tó ń jẹ́ ẹran ara èèyàn tí wọ́n tún ń tà ẹ̀yà ara èèyàn

Afurasi to n jẹ ẹran ara eeyan

Oríṣun àwòrán, Shehu Mohammed

Ileeṣẹ Ọlọpaa Naijiria ti fi panpẹ ofin mu eeyan mẹrin kan ti wọn furasi pe wọn n jẹ ẹran ara eeyan wọn si n ṣe katakara awọn ẹya ara eeyan.

Eyi jẹ ohun to ṣọwọn gidi gan paapaa ni apa Ariwa orilẹede Naijiria orilẹede Naijiria, ipinlẹ Zamfara to ti waye.

Kọmisọna Ọlọpaa ipinlẹ naa, Ayuba Elkanah s fun awọn oniroyin ni ilu Gusau ni Ọjọbọ ọsẹ pe awọn afurasi naa bọ si awọn lọwọ lẹyin ti wọn ri oku kan ninu ile akọku kan ti wn si ti yọ lara awọn ẹya ara wọn lọ.

Lasiko ti wọn n ṣe iwadii lọwọ nipa pipoora ọmọ ọdun mẹsan kan nilu ni awọn ọlọpaa ṣawari awọn afurasi yii ati iṣẹ aburu ti wọn n ṣe.

Elkanah sọ fun awọn oniroyin pe ni jọ Kejila oṣu Kejila ni Ọgbẹni Ali Yakubu Aliyu wa sọ ni Agọ awọn pe oun n wa ọmọ oun, Ahmad Yakubu to jẹ ọmọ ọdun mẹsan.

Kete ti wọn gba iroyin yii lo ni awọn Ọlọpaa tu sita lati bẹrẹ iṣẹ ati iwadii lori ọrọ naa.

Ni ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Kejila ọdun 2021 ni awọn ọlọpaa ọtẹlmuyẹ ni awọn gba itanilolobo kan pe oku eeyan kan wa ti wọn ri ninu ile akku kan lagbegbe Barakallahu ni Gusau ti wọn so ẹsẹ mejeeji ati ọwọ pẹlu akisa ti wọn si fi ọra bo ori rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Awọn afurasi ọhun jẹ ọkunrin meji ati awọn ọdọlangba meji ti ọwọ si tẹ wọn lọsẹ to kọja.

Gẹgẹ bi ọga ọlọpaa ṣe sọ, wọn ti n ṣe akitiyan lati rii daju pe awọn afurasi to ku ti wọn jọ n ṣiṣẹ yii ko si panpẹ ofin.

“Nibayii, iwadii ti fihan pe lẹẹmeji, olori awọn afurasi ọhun san iye owo ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira fun ẹya ara eeyan.

Iroyin ni jijẹ tabi ṣiṣe katakara ẹya ara eniyan ko wọpọ ni ipinlẹ Zamfara. Ṣugbọn o jẹ apa ibi kan lorilẹede Naijiria ti ipaniyan ati ijinigbe fi gba owo ti wọpọ gidi ti awọn eeyan si n bu ẹnu atẹ lu awọn alaṣẹ ilu pe wọn ko koju iṣoro yii.

Ẹwẹ, ninu ipade oniroyin kan to waye l’Ọjọbọ ọsẹ, Kọmisọna Ọlọpaa Ayuba Elkanah sọ pe ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ni arakunrin ti wọn mu yii.

O ni Baba n gbimọ pọ pẹlu awọn mẹta mii lati maa ta ẹya ara eeyan ni N500,000 fun eeyan kan.

Gẹgẹ bi wọn ṣe darukọ wọn, yatọ fun Baba, awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ ni Abdulzhakur Mohammed, ẹni ogun ọdun, Buba, ẹni ọdun mẹtadinlogun ati Tukur ẹni dun mẹrinla.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ