Bí EFCC ṣe mú ayédèrú ọ̀gágun sọ́jà Bolarinwa tó tún ní ẹ̀sùn jìbìtì owó N270m

FAKE SOLDIER, BOLARINWA OLUWASEGUN

Oríṣun àwòrán, EFCC. TWITTER

Ọwọ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC ti tẹ ayederu ọgagun sọja kan, Bolarinwa Oluwasegun lori ẹsun jibiti N270m.

Afurasi ọhun ni a gbọ pe o n pe ara rẹ ni ọgagun ni ileeṣẹ ọm’ogun orilẹede Naijiria.

Ati wipe o purọ fun ileeṣẹ Kodef to n ri si kiko ẹru jade lati ibudokọ oju omi pe Aarẹ Muhammadu Buhari ti fẹ yan oun gẹgẹ bí olori ọmọ ogun orilẹ, COAS.

FAKE SOLDIER, BOLARINWA OLUWASEGUN

Oríṣun àwòrán, EFCC. TWITTER

Ọgbẹni Olusegun sọ fun ileeṣẹ Kodef pe oun nilo iranwọ owo lati rii pe Buhari foun ni ipo naa.

A gbọ wipe afurasi yii kọ lẹta ayederu iyansipo gẹgẹ bi olori ọm’ogun orilẹ lorukọ aarẹ eleyii to fihan ẹni to lu ni jibiti gẹgẹ bi ẹri.

Gẹgẹ bi atẹjade ti EFCC fi sita, Ọjọru ọjọ kejila oṣu kinni ọdun 2021 yii ni ajọ naa gbe afurasi ọhun nile rẹ lagbegbe Alagbado niluu Eko.

Awọn nkan ti wọn ri ni ile rẹ ni ibọn mẹfa, ọta ibọn mẹta, ọpa ati oriṣiiriṣii ayederu iwe.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ