Ọ̀rọ̀ Japa dé Ekiti; ‘Iléeṣẹ́ tó ní àwọn fẹ́ ran wá lọ́wọ́ lọ ìlú Òyìnbó ti “scam’ wa, àìsàn déé!

Awọn onijibiti kan ti lọ lu awọn ara ipinlẹ Ekiti ni jibiti owo latari ṣiṣeleri fun wọn lati ba wọn ṣe ọna ati rinrinajo lọ si ilu oke okun.

Iléeṣẹ́ tó ní àwọn ń ran èèyàn lọ́wọ́ láti lọ ìlú òyìnbó yìí lo n jẹ VAST-OTURAREBI.

“Wọn ò dàbíi oníjìbìtì ènìyàn, bí wọ́n ṣe ń bá wa sọ̀rọ̀, ẹ̀yin gan ẹ máa fẹ́ gba fọ́ọ̀mù ọ̀hún, awọn to n ba wọn ṣiṣẹ “look responsible.”

Awọn ara Ekiti

Lara awọn ọkunrin toun naa fori ko jibiti yii sọ fun wa pe tori pe owo naa ko fi bẹẹ pọ -N58,000 loun ẹ kara bọọ.

O ni oun gan o ba ti ba ara oun nileewosan bii awọn mii ka ni owo ti oun ko sibẹ to bii miliọnu kan si meji ni. Amọ oun ṣe ọkan ọkunrin.

Fọọmu ayederu lati lọ ilu Oyinbo

Arabinrin kan naa ni “gbogbo wa la gbagbọ pe lootọ ni taa si gba fọọmu ọhun.

Wọn sọ fun wa pe iṣẹ ti wa lọhun koda pe ile ti a maa de si naa ti wa nile ati pe irọrun ni a maa fi san owo to ba yẹ ka san pada.

Nibi ti wọn ṣalaye fun wọn de, iyalẹnu lo jẹ fun wa pe wọn tilẹ le ṣalaye gbogbo ilana ti wọn tẹle lati kọwọ bọ fọọmu naa.

Ileeṣẹ Ayederu

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí