Ìdí tí ọ̀wọ́ngógó epo fí wà ní Naijiria nìyíí…

Aworan

Ijọba orilẹede Naijiria ti kede idi ti ọwọngogo epo fi gbode kan.

Minista fun ọrọ epo bẹntiro ni Naijiria, Timipre Sylva  lo fi iroyin naa leke lasiko to n ba BBC Pidgin sọrọ lowo ọwọngogo epo bẹnitirol to n waye kaakiri orilẹede Naijiria.

Sylva ni awọn to n ta epo yii n lọ ọrọ omiyale agbara ya ṣọọbu lati fi da ọwọngogo epo bẹntiro silẹ.

Owọngogo epo ọhun mu ki awọn ọlọkọ gba gbogbo oju ọna, eyi to tun n fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju popo.

‘’O ṣẹni laanu pe awọn eniyan lo n fa ọwọngogo yii’’

Aworan

Minisita naa ni lootọ ni ọjọ rọ ni Lọkọja, ti omi si pọ ni ọna ti ko si si ọkọ nla kankan to le kọja ayafi ki wọn gba ọna miran.

‘’Pupọ ninu wọn n gba ọna miran amọ wọn n gbe epo pamọ.’’

Ohun ti wọn n ṣe ni pe wọn n gbe epo pamọ ki awọn eniyan le san owo pupo lati ri epo ra.

Lati bi oṣu kan ṣẹyin ni awọn ilu ni Naijiria ti n koju aisi epo ati ọwọngogo epo bẹntirol

Bakan naa ni Minisita naa fikun un pe ti awọn ba gbe igbeṣẹ tako awọn to n ta epo naa yoo tun buru ju ti tẹlẹ lọ.

Minisita naa wa rọ awọn eniyan lati fi iye denu pe yoo dopin laipẹ.