Fídíò, “Ọ̀pọ̀ ń gbàdúrà kí àwọn ní HIV báyìí”, Duration 2,00

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

WORLD AIDS DAY 2018: HIV/ AIDS kìí ṣe ìdájọ́ ikú mọ́

Ọjọ kini oṣu kejila ọdun ni ajọ iṣọkan agbaye ya sọtọ fun sisami ayajọ igbogun ti kokoro arun HIV ati arun AIDS gan an funra rẹ lagbaye.

Lara awọn akori ti wọn ti lo sẹyin ri ni “Mọ bi o ti ri lori arun naa.”

Ohun meji ni ajọ ilera agbaye, WHO n gbe soke lori ayajọ ti ọdun yii; akọkọ ni rirọ awọn eeyan lati lọ ṣe ayẹwo wọn ki wọn lee mọ boya wọn ni kokoro arun naa tabi wọn ko ni, ki wọn si lee ṣamulo awọn ohun elo itọju ati idaabobo ara ẹni lọwọ kokoro arun naa.

Ikeji ni rirọ awọn alaṣẹ lati gbe eto ‘ilera fun gbogbo eniyan’ larugẹ.

Lara awọn alamojuto eto naa ni ipinlẹ Eko, Adebayọ Aladeyẹlu, to jẹ alaga apapọ ajọ to n gbogunti HIV/AIDS ba BBC News Yoruba sọrọ lori awọn ibi ti ọrọ de duro lori ipolongo ati gbigbogun ti arun naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: