Ìdílé mùsùlùmí ẹlẹ́ni méje na ọmọbìnrin tó lọ ṣọ́ọ́ṣì ní pàsán ọgọ́rùn-ún, wọ́n dèrò àtìmọ́lé

Shakira ati awọn to n na a ni pasan

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ara mee riri, mo ri ori ologbo lori atẹ ni isẹlẹ kan to waye lorilẹede Uganda eyi to n fa awuyewuye bayii.

Olori idile naa, Jaberi Higenyi ati eeyan mẹfa ninu idile rẹ ni ijọba ti gbe si atimọle nitori fidio kan to gba ori ayelujara kan, ninu eyi ti wọn ti huwa aitọ.

Ọmọdebinrin kan ẹni ọdun mejidinlogun, Shakira Naula ni fidio naa se afihan rẹ pe Jaberi ati awọn eeyan kan n to ẹgba to to ọgọrun si nidi.

Bi awọn ọ̀kunrin kan mu ọmọdebinrin naa ni ẹsẹ, ni awọn miran mu ni ọwọ mejeeji , ko maa baa salọ lasiko ti wọn n to pasan naa si lara.

Fidio naa lo fa ariwo lori ayelujara, ti ọ̀pọ eeyan si n beere pe ki ni ọmọdebirin naa se to bẹẹ, to fi di ẹni iya bayii.

Iwadii si fihan pe Shakira lọ bawọn peju nile ijọsin kan, Kibuku Parayer Convention Church lati se isin, eyi to wa labẹ idari Pasitọ Bicholas Kitibwa.

Shakira ati awọn to n na a ni pasan

Oríṣun àwòrán, Screen shot

“Mama Shakira ni wọn lo n sisẹ nilẹ Saudi Arabia, to si fi ọmọ rẹ̀ sabẹ itọju Ziyadi Musener”

Awọn eeyan inu ẹbi naa, ti wọn n gbe ni abule Bwase kinni, ẹkun Bugolya, lagbegbe Kadama nilu Kibuku naa, ni wọn koro oju si iwa Shakira yii nitori pe o tako ẹsin musulumi to n se.

Awọn ikọ alaabo nilu Kibuku, to fi mọ kọmisana ọlọpaa nilu naa, lo lọ mu Hingeyi atawọn mọlẹbi rẹ, ti wọn dawọ jọ lu Shakira tori pe o lọ si sọọsi.

Orukọ awọn mọlẹbi yoku ti ọwọ ọlọpa ba ni Yusufu Nantege ẹni ọdun mejidinlọgbọn, Muhammad Wapesa ẹni ọdun mẹrinlelogun ati Jaberi Lumans, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn.

Awọn yoku ni Uthuman Koosu ẹni ọdun mẹẹdọgbọn ati Issa Wasereye, ẹni ọdun mẹrinlelogun.

Mama Shakira ni wọn lo n sisẹ nilẹ Saudi Arabia, to si fi ọmọbinrin naa sabẹ itọju Ziyadi Musenero, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, ti ijọba si ko obinrin naa atawọn eeyan yoku to lu Shakira.

Shakira ati awọn to n na a ni pasan

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Ileesẹ ọlọpa ni labẹ ofin orilẹede Uganda, agbalagba ni ọmọ to ba ti pe ọdun mejidinlogun, to si lẹtọ lati se ẹgbẹkẹgbẹ tabi ẹsinkẹsin to ba wu u lati se

Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ naa, adele fun agbẹnusọ ileesẹ ọlọpa lẹkun ariwa Bukedi, Samuel Semewo fi ọwọ sọya pe ileesẹ ọlọpaa wa lori ẹsun naa bo se yẹ.

O ni labẹ ofin orilẹede Uganda, agbalagba ni ọmọ to ba ti pe ọdun mejidinlogun, to si lẹtọ lati se ẹgbẹkẹgbẹ tabi ẹsinkẹsin to ba wu u lati se.

Bi wọn si se n na ọmọdebinrin naa, wọn fẹ fi tipa gbe ẹsin le Shakira lori ni lodi si ofin orilẹede naa.

“Obi le fun ọmọ rẹ ni ẹgba meji tabi mẹta lati ba a wi amọ ki wọn so ọmọ mọlẹ tabi fi tipa mu u ni ọwọ ati ẹsẹ lasiko ti wọn n na a ni pasan jẹ iwa ifiyajẹni ati ọyaju si ni.”

Semewo wa rọ awọn obi lati maa wa ọna miran fi bawọn ọmọ wọn wi dipo fifi iya jẹ wọn lọna aitọ.

Bakan naa, Sowed Looki, tii se asoju ilu Kibuku ninu igbimọ ẹlẹsin Islam to ga julọ nilẹ Uganda, naa koro oju si iwa ti mọlẹbi naa hu, to si se apejuwe rẹ bii eyi to kan ni labuku pupọ, to si lodi si ilana ẹsin Islam.

O wa fi anọbi Nuhu se apẹrẹ ninu iwe mimọ Kurani, ti ọmọ rẹ kọ lati tẹle ilana ikọni baba rẹ lati wọnu ọkọ to kan am ti Allah sọ fun pe ko jọwọ ọmọ naa lati maa lọ.