Òjò àti ìjì líle wó ògiri ọgbà ẹ̀wọ̀n Suleja, ẹlẹ́wọ̀n 119 sálọ

Ọgba ẹwọn ti wọn fọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ko din ni ẹlẹwọn mọkandinlọgọfa (119) to ti sa kuro lọgba ẹwọn Suleja, to wa lẹba ilu Abuja, to jẹ olu ilu Naijiria.

Iṣẹlẹ yii lo waye latari iji lile to wo apakan odi ẹwọn naa lẹyin ojo rọ lagbegbe naa lalẹ Ọjọru.

Igbakeji adari ileeṣẹ ọgba ẹwọn lagbegbe FCT, AS Duza lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade kan.

O ni “ojo nla kan rọ fun ọpọ wakati lalẹ Ọjọru, ọjọ kẹrinlelogunm, oṣu Kẹrin, ọdun 2024, eyii to ba nnkan jẹ ni ọgba ẹwọn to wa ni Suleja, nipinlẹ Niger.

“Yatọ si ọgba ẹwọn naa, awọn ile kan to sunmọ ọgba ẹwọn ọhun tun faragba ninu iṣẹlẹ naa eyii to fun awọn ẹlẹwọn ti apapọ wọn jẹ mọkandinlọgọfa lanfani ati salọ.

Duza ṣalaye pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati ri pe ọwọ ofin pada tẹ awọn ẹlẹwọn naa, awọn si ti nawọ gan mẹwaa lara wọn.

Ọgba ẹwọn

Oríṣun àwòrán, getty images

O ni “pẹlu ajọsẹpọ awọn ileeṣẹ eto abo mii, ati mu mẹwaa ninu awọn ẹlẹwọn to salọ, a si ti n tọpinpin awọn to ku.”

Gẹgẹ bii ohun to sọ, asiko ti Naijiria wa labẹ isinru awọn alawọ funfun ni wọn kọ ọgba ẹwọn ọhun, awọn ogiri rẹ ko si lagbara bii ti atijọ mọ.

Yatọ si ọgba ẹwọn yii, ojo naa tun ba awọn ile kan jẹ lagbegbe ilu Abuja.

Ẹnikan to n gbe ni Suleja ọhun, Babangida Turaki sọ fun awọn akọroyin pe ogiri to wo yii wa lara awọn eyii ti wọn ṣẹṣẹ n ṣatunṣe rẹ.

Wayi o, nnkan ti n pada bọ sipo ni Suleja bayii lẹyin ti awọn ẹlẹwọn naa salọ, awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn si ti tẹsiwaju lati maa wa awọn to salọ.

Iṣẹlẹ yii lo n waye lakoko ti jọba apapọ n gbiyanju lati din iye eeyan to wa ninu ọgba ẹwọn ku.