Àlàyé rèé lórí ìdí tí Amẹ́ríkà ṣe fẹ́ fòfin de TikTok

Aworan awọn olufẹhonuhan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Diẹ bayii loku ti orilẹede Amẹrika yoo fi fofin de itakun ayelujara TikTok.

Idi abajọ ni pe ile aṣofin agba orilẹede naa ti buwọlu abadofin ti yoo fofin de aapu ọhun, ayafi ti ileeṣẹ China, ByteDance to ni itakun ayelujara naa ba le ta a loku.

Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu awọn eeyan lo n lo TikTok ni wọn n fi pin fidio, amọ, ọpọ lo ti n kọminu lori bi awọn nnkan to jẹ aṣiri nipa awọn to n lo aapu naa ko ṣe ni lu sita.

Bakan naa lawọn eeyan mii tun n bẹru pe TikTok ni ajọṣaepọ pẹlu ijọba China niluu Beijing.

Ni bayii, ile aṣofin agba ati ile aṣoju-ṣofin ti buwọlu aba ti yoo fofin de TikoTok l’Amẹrika.

Koda, Aarẹ Joe Biden ti ṣeleri lati buwọlu abadofin naa ki o le dofin.

Awọn wo lo fẹ fofin de TikTok l’Amẹrika, kin ni idi abajọ?

Awọn ọmọ ile aṣofin mejeeji l’Amẹrika lo ti buwọlu aba lati fofin de TikTok, ayafi ti ByteDance ba le ta a fun ileeṣẹ mii ti kii ṣe ti China loku.

Awọn aṣofin n bẹru pe ijọba China le gba data miliọnu mẹtadinlogun awọn ọmọ ilẹ Amẹrika to n lo TikTok silẹ

Ni ọjọ kókanlelogun oṣu Kẹrin yii ni awọn aṣofin buwọlu $95bn gẹgẹ bi owo iranwọ fun orilẹede Ukraine, Israel ati Taiwan to jẹ orilẹede toun naa fọwọ si tita aapu TikTok.

Ni ọjọ kẹtalelogun ni ile aṣofin agba l’Amẹrika buwọlu ofin yii, ohun toku ni ki wọn fi abadofin naa ṣọwọ si Aarẹ Biden.

Ẹwẹ, Aarẹ Amẹrika tẹlẹ ri, Donald Trump naa gbiyanju lọdun 2020 lati fofin de TikTok lasiko ijọba rẹ.

Igba wo ni fifi ofin de TikTok l’Amẹrika le ṣẹlẹ?

Aworan foonu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kii ṣe lẹsẹkẹsẹ ti Aarẹ Biden ba ti buwọlu abadofin naa ni ofin yii yoo mulẹ.

Koda, o maa to ọpọlọpọ ọdun ko to di pe awọn eeyan Amẹrika ko ni lanfani lati lo TikTok mọ.

Idi ni pe ileeṣẹ ByteDance naa yoo gbe ọrọ ọhun lọ sile ẹjọ eyi to si le de ile ẹjọ to ga julọ.

Bakan naa ni ofin fun ileeṣẹ ByteDance ni oṣu mẹsan an lati ta TikTok fun ọmọ ilẹ Amẹrika, pẹlu anfani oṣu mẹta mii.

Lẹyin naa ni ofin to de TikTok yoo fẹsẹ mulẹ.

Eleyii tumọ si pe ọdun 2025 ni gbedeke igba ti ByteDance yoo ta TikTok, lẹyin eto idibo gbogbogbo ọdun 2024.

Ero awọn alaṣẹ TikTok lori igbesẹ Amẹrika lati fofin de aapu naa ree

Aworan ọgaagba TikTok

Oríṣun àwòrán, Getty Images

TikTok ti n kọminu lori igbesẹ ijọba Amẹrika lati fofin de aapu naa, wọn ni igbesẹ naa tabuku ofin Amẹrika to fawọn eeyan lanfani ati le sọrọ nibi kibi lai bẹru.

Ọgaagba ileeṣẹ TikTok, Shou Zi Chew ti kilọ pe fifi ofin de TikTok yoo ro awọn itakun ayelujara mii lagbara, yoo si tun jẹ ki ẹgbẹẹrun eeyan padanu iṣẹ wọn.

Ileeṣẹ ByteDance yoo ni lati gbaṣẹ lati ọdọ awọn oṣiṣẹ ijọba China kan ki wọn to le ta TikTok, ṣugbọn Beijing ti pinnu pe oun yoo tako igbesẹ naa to ba le waye.

Awọn orilẹede wo ni wọn ti fofin de TikTok?

Ti abadofin ile igbimọ aṣofin Amẹrika ba di ofin tan, yoo jẹ awokọṣe fawọn orilẹede mii naa lati fofin de TikTok.

Orilẹede India ti kọkọ fofin de TikTok, ṣaaju akoko yii, India jẹ ọja TikTok to tobi julọ ki ijọba orilẹede naa to fofin de e lọdun 2020.

Bakan naa, orilẹede Somalia, Nepal, Afghanistan ati Iran naa ti fofin de TikTok.

Ijọba Uk ati ile igbimọ aṣofin rẹ naa fofin de lilo TikTok gẹgẹ bi ọkan lara awọn aapu tawọn oṣiṣẹ n lo lọdun 2023, ajọ EU naa ṣe bẹẹ.

Koda, ileeṣẹ iroyin BBC naa rọ awọn oṣiṣẹ rẹ lati yọ TikTok kuro lori foonu ọọfiisi wọn tori eto aabo.