Ọ̀pọ̀ tó ro Super Falcons pin ní ìdíje World Cup tó kọjá la jọ lójú ní Australia – Asisat Oshoala

Ikọ agbabọọlu obinrin Naijiria, Super Falcons kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye fun awọn agbabọọlu obinrin tọdun 2023.

Idije naa waye ni orilẹede Australia nibi ti Falcons ti ja kuro ninu idije naa ni ipele keji lẹyin ti England bori ninu pẹnariti ti wọn gba lẹyin ti wọn ta ọmi ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Lara awọn odu agbabọọlu to gba bọọlu fun Naijiria ninu idije ọhun ni Asisat Oshoala, to n gba bọọlu jẹun pẹlu ikọ agbabọọlu obinrin Barcelona femeni.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Oshoala ṣalaye pe inu awọn agbabọọlu naa dun pe oju ko ti wọn kuro nibi idije naa.

O ni bi o tilẹ jẹ wi pe ipele keji ni aga ti yẹ mọ awọn nidi, sibẹ awọn ja fitafita lati jade gẹgẹbi akin.

Ki lawọn ẹbi rẹ sọ si bo ṣe ṣe ajọyọ goolu rẹ?

Asisat Oshoala

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lara awọn nnkan manigbagbe to waye lasiko idije naa fun Asisat Oshoala ni bi o ṣe bọ aṣọ rẹ lati ṣe ajọyọ goolu to gba wọ awọn ikọ Australia.

Oshoala nilootọ o ri bakan ṣugbọn awọn mọlẹbi oun mọ pe oun ko lee pa idunu oun mọra mọ lo mu ki oun bọ aṣọ.

O fi kun un pe niwọn igba to jẹ wi pe ko si aṣemaṣe kankan to rọ mọ eyi, ko si idi kan tabi omiran fun oun lati gbe eyi sọkan.

Ọpọ ni ko gbagbọ pe a le ṣe nnkan to jọju ni idije World cup naa – Oshoala

Asisat atawọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu kan

Ninu ọrọ rẹ, Asisat Oshoala tun ṣọrọ nipa igbaradi fun idije naa.

O ni ṣaaju idije ife ẹyẹ agbaye naa, ko si ẹnikẹni to lero pe awọn lee gbẹyẹ ni ipin ti awọn wa.

Orilẹede Australia, Canada, ati Ireland lo wa ninu ipin ti Falcons ba ara wọn ni ipele akọkọ.

Awọn ọjọ̀ẹwẹwẹ agbabọọlu  kan n sare

O ni ọpọ eeyan ni ko gbagbe pe awọn le kọja ipele akọkọ yii ninu idije oun ti inu awọn si dun pe awọn ja fitafita fun ati lọ si ipele kẹta si aṣekagba ki orilẹede England to daṣọ bo ile pa wọn.

O wa rọ awọn ọmọdebinrin ti wọn ba ni ifẹ si ati gba bọọlu pe ki wọn maa ri i daju pe wọn tẹpa mọ gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe yala ko jẹ nipa ere idaraya tabi nnkan miran.