Wọ́n bá òkú olùbádámọ̀ràn Sẹ́nétọ̀ lẹ́gbẹ́ títì, ẹbí pè fún ìdájọ́ òdodo

Adeniyi Sanni

Oríṣun àwòrán, Others

Àwọn ẹbí, ará àti ọ̀rẹ́ ti ń kọrin arò lẹ́yìn olóògbé Adeniyi Sanni tí ìgbàgbọ́ wà pé àwọn kan dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.

Adeniyi Sanni kó tó dágbére fáyé ló jẹ́ olùrànlọ́wọ́ sí Sẹ́nétọ̀ Solomon Adeola tó ń ṣojú ẹkùn Iwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Ogun ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà Nàìjíríà tó wà ní ìlú Abuja.

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ olóògbé náà ṣẹ̀yẹ orin ìkẹyìn fún un ní Awoniyi Jones Avenue ní agbègbè Ikeja ní ìpínlẹ̀ Eko.

Ní ọjọ́rú ni ètò ìsìnkú náà yóò wáyé ní itẹ́ òkú Redemption Camp tó wà ní òpópónà márosẹ̀ Èkó sí Ìbàdàn, Mowe ìpínlẹ̀ Ogun lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣètò ìsìn fún un tán ní ilé ìjọsìn Redeemed Christian Church, Rhema Chapel.

Ìròyìn ní òwúrọ̀ ọjọ́ Karùn-ún oṣù Kẹjọ, ọdún 2023 ni àwọn kan ṣekúpa Sanni ní ìpínlẹ̀ Eko.

Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ olùbádámọ̀ràn Sẹ́nétọ̀ Solomon Adeola lórí ètò ìròyìn, Kayode Odunaro ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ló dá Sanni dúró ní agbègbè Ojodu nígbà tó ń lọ sí ilé rẹ̀ ní Isheri, ìpínlẹ̀ Eko.

Odunaro ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò bèèrè fún àwọn ìwé ọkọ̀ lọ́wọ́ Sanni èyí tó ní ìyàwó rẹ̀ fi ránṣẹ́ sí í pẹ̀lú ẹ̀rọ WhatsApp.

Ó ṣàlàyé pé lẹ́yìn tó pẹ́ díẹ̀ ni ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní pe gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ̀ rẹ̀ pé òun kò gbúròó ọkọ̀ òun mọ́.

Ó ní èyí ló fà á tí gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní wá a.

Àtẹ̀jáde náà tẹ̀síwájú pé àwọn kan ló pe ìyàwó Sanni nígbà tí wọ́n rí òkú rẹ̀ ní agbègbè Toyota Bus stop ní Oshodi pẹ̀lú ojú ọgbẹ́ ọta ìbọn lára.

Nínú àtẹ̀jáde mìíràn lọ́jọ́ Ajé, Sẹ́nétọ̀ Adeola tún fẹ̀sùn kan pé àwọn ọmọ ogun ti Iléeṣẹ́ ológun Commander 9 Brigade, Ikeja ló ṣekú pa Sanni.

Iléeṣẹ́ ìròyìn Punch ní nígbà tí àwọn kàn sí Agbẹnusọ Iléeṣẹ́ ológun tó wà ní Victoria Island, Colonel Olabisi Ayeni kò fèsì sí ìbéèrè tó sì ní òun yóò kàn sí wọn padà.

Odunaro ní ikú Sanni jẹ́ àdánù ńlá fún àwọn nítorí láti bí ogún ọdún sẹ́yìn ló ti wà pẹ̀lú Sẹ́nétọ̀ Adeola.

Ó júwe olóògbé náà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní ìfarajìn sí iṣẹ́ rẹ̀.

Ọ̀kan nínú àwọn ẹbí olóògbé ní kí ìjọba báwọn ṣe ìwádìí, kí wọ́n sì fi ojú àwọn tó wùwà ibi náà winá òfin.