Àjọ Africa Union fòfin de Niger lórí ẹ̀sùn ìdìtẹ̀gbàjọba

AU

Oríṣun àwòrán, getty images

Ajọ isọkan ilẹ Adulawọ lọjọ Isẹgun kede pe oun ti fofin de orilẹede Niger titi ìjọba alagbada yoo fi pada si orilẹede naa.

Ẹka alaafia ati abo rọ ajọ AU lati gbe igbesẹ ati iwadi lori ọrọ aje ati awọn ijamba tí ríran ọmọ ogun si Niger kí wọn si fesi pada fun ajọ naa.

Saaju ni awọn ọmọ ologun ti kọkọ yọ Aarẹ Mohamed Bazoum kuro lori oye lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu keje eyi to bí ajọ ECOWAS nínu, ti wọn dunkoko pe àwọn yoo doju ogun kọ orilẹ-ede Niger.

Ajọ ECOWAS ni forikori pe àwọn yoo ṣeto lati ko awọn ọmọ ogun kalẹ lati gba ìjọba lọwọ ijọba ologun lorilẹ-ede Niger.

O ni oun ti setan lati gbe igbesẹ ti awọn ologun ni Niger ba kọ lati gbe ijọba silẹ pẹlu alaafia.

AU ninu ipade to ṣe lọsẹ to kọja jiroro lori awọn ijamba to le waye ti awọn ologun ba da si ọrọ orilẹede Niger.

Iditẹgbajọba yii lo ti fa ọpọlọpọ awuyewuye lagbaye to si jẹ pe o fẹ ni ọwọ awọn ìkọ ologun alakatkiti ẹṣin Al-Qaeda ninu.

Niger ni orilẹede kẹrin tí yoo koju iditẹgbajọba laarin ọdun mẹta lẹyin orilẹede Burkina Faso, Mali ati Guinea.

Awọn olori ìjọba ni Burkina Faso ati Mali tí wa jẹ ko di mimọ pe awọn ṣetan lati ti orilẹede Niger lẹyin ti ikọ ologun ECOWAS ba ṣe ikọlu si i.

Iitẹgbajọba yii jẹ ẹlẹkarun un ninu itan lorilẹede Niger lati igba ti wọn ti gba ominira lọwọ France.

Eto idibo to gbe Bazoum wọle bii Aarẹ lọdun 2021 jẹ gbigbe ìjọba kalẹ ni ilana alaafia lorilẹ-ede naa.

Aarẹ Bazoum ati awọn mọlẹbi rẹ lo wa ni ahamọ ikọ ologun orilẹ-ede Niger bayii lati igba ti iditẹgbajọba naa ti waye.