Ooru àmújù gbẹ̀mí èèyàn tó lé ní 100, wọn ò ríbi gbé òkú sí mọ́

Aworan awọn oku

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kò dín ní èèyàn ọgọ́rùn-ún tó ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní orílẹ̀ èdè Mali látàrí bí ìlú náà ṣe ń gbóná janjan láti oṣù tó kọjá.

Ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá, òòrùn tó ń mú ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìlú Kayes wọ 48.5°C.

Èyí ni òòrùn tó mú jùlọ nílẹ̀ Adúláwọ̀ tó wà ní àkọ́ọ́lẹ̀ nínú Kẹrin ọdún 2024 gẹ́gẹ́ bí ohun tí àwọn àjọ tó ń rí sí ojú ọjọ́ kan ṣe sọ.

Àwọn aláìsàn tó lé ní 102 tí ooru àmújù náà dà láàmú ni wọ́n gbé lọ sí ilé ìwòsàn Gabriel-Toure tó wà ní Bamako, olú ìlú orílẹ̀ èdè Mali, iléeṣẹ́ ìròyìn FRI sọ.

Adarí ẹ̀ka kan ní ilé ìwòsàn náà, Djibo Mahamane Django sọ fún àwọn akọ̀ròyìn iléeṣẹ́ rédíò Joliba FM pé ọ̀pọ̀ àwọn aláìsàn náà ni wọ́n ti lé ní ọgọ́ta ọdún.

Àwọn èèyàn kan sì ń sọ pé iye èèyàn tó ti àdánù ẹ̀mí wọn láàárín ọja mẹ́ta ti lé ní 250.

Olùdarí ilé ìgbóòkúpamọ́sí kan, Ladji Dibatere sọ pé àwọn èèyàn tó ń kú ń pọ̀si àti pé k[]o sí ààyè ní mọ́ṣúárì mọ́.

Dibatere ní ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn lọ ń gbé òkú àwọn èèyàn wọn pamọ́ sílé.

Àwọn aláṣẹ rọ àwọn ènìyàn láti máa dúró síbi tí atẹ́gùn bá wà dada, tí wọ́n sì ṣe àyípadà àkókó àwọn ilé ẹ̀kọ́ pàápàá ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ́dé àti arúgbó ni ooru náà ń dàmú púpọ̀

Kí ni àwọn nǹkan tí èèyàn lè ṣe láti bọ́ lọ́wọ́ ooru àmújù yìí?

Eeyan to n da omi sori

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àwọn ọmọdé àtàwọn arúgbo ni ó ṣeéṣe kí wọ́n fara kásá ìjàmbá ooru àmújù tó ń mú lásìko bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo èèyàn náà ló lè ṣàkábá fún.

Adarí ẹ̀ka ìmọ̀ Geography ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Rivers State University, Ọ̀jọ̀gbọ́n Precious Ede gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn láti ṣe àwọn nǹkan láti móríbọ́ lọ́wọ́ ìpalára tí ooru lè fà.

  • Kí a máa ṣí fèrèsé sílẹ̀ kí atẹ́gùn le máa ríbi wọlé.
  • Kí a máa mú omi dada láti fi pàrọ̀ omi ara tó ń jáde látara bí èèyàn ṣe ń làágùn.
  • Kí èèyàn jìnà sí àwọn iṣẹ́ tó lè máa mú èèyàn làágùn púpọ̀ pàápàá ṣíṣe eré ìdárayá lápọ̀jù.
  • Wíwọ àwọn aṣọ tó bá fẹ́lẹ́ tí wọ́n fi òwú ṣe tí atẹ́gùn le máa máa gba ibẹ̀ wọlé sára dípò àwọn aṣọ onírọ́bà.
  • Lílo ẹ̀rọ amúlétutù láti fi máa mú ilé tutù dada.