Ẹ̀gbin pọ̀ nínú iṣẹ́ mi ṣùgbọ́n mo ní àmójúkúrò – Bashir Alabi

Yoruba bọ wọn ni idi iṣẹ ẹni lati mọ ni lọlẹ,

Ọpọ awọn ololufẹ ere boolu lorilẹede Naijiria paapa awọn ololufẹ Super Eagles ati Kwara United ni yoo mọ Bashir Ahmed Alabi.

Bashir Ahmed Alabi, ẹni ti ọpọ mọ si Arabambi jẹ apanilẹrin ere idaraya boolu alafẹsẹgba ni Naijiria.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, Alabi ni ọpọ eeyan lo ma ri oun gẹgẹ bi ọkunrin to ma kun nnkan soju bi ẹni ti ko ni laakaye rara.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmed

O ni oun nifẹ ere boolu pupọ ti ọpọlọpọ eeyan ko si mọ pe oun gba boolu ri.

“Lati kekere ni mo ti n lọ si ode ariya, ma maa jo, ma maa ṣe awada.

“O ti mọ mi lara gan pe ki ma kun nnkan soju.”

Alabi ni iṣẹ Carpenter ni oun ṣe tẹlẹ sugbọn nigba ti oun ti kọ ibi ara si bi bọọlu yii, ni oun ti dupẹ fun Ọlọrun.

“Ni ibi iṣẹ bọọlu yii, a kọ ile nibẹ, a dẹ tun ra mọtọ.”

“Ore ọfẹ ni mo ni nitori wọn ko nifẹ iṣẹ mi ni Ilorin”

Alabi ni ọpọ igba ni awọn eeyan ti kesi Baba oun nitori pe wọn nifẹ iṣẹ ti oun ṣe.

“Wọn lọ ba Baba mi ni ile pe ọmọ Alfa, Basiru, o tun wa n ku oju laarin ọpọ ero, ko ma ni ojuti.

“Wọn ti rii ni iri ọlẹ tabi ẹni ti ko lojuti, Amọ isẹ ni.”

O tẹsiwaju pe ọpọ awọn ololufẹ oyinbo lo fẹran oun paapa o ni oludije aarẹ ninu eto idibo to kọja, Peter Obi n wa oun kiri lati ba ya foto.

“Awọn eeyan n wo bi ọlẹ, kii ṣe iṣẹ ọlẹ nitori nnkan ti a kun si ara gan o n gbona lara, bii pe eeyan dana si ara ni.”

“Awọn Oyinbo gan ko mi jẹ, wọn n wa mi kiri, ti n ko ba ti de si ori paapa bayii, wọn o maa beere mi lọwọ to ku ni pe ni bo mo wa.

“Ẹni to fẹ ṣe aarẹ tẹlẹri yẹn, (Peter Obi), o n wa mi kiri o dẹ tun ba mi ya fọto.”

Ọrọ pọ lẹnu Bashir Ahmed Alabi lori irinajo rẹ, ẹ wọ yii, kẹ gbadun rẹ

Aworan

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmed

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí