Oluwo sọ ọmọ tuntun rẹ̀ ní orúkọ ńlá kan, ẹ wà tú u wo, ẹ wo orùkọ́ aràmàǹdà!

Oluwo ati iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Alayeluwa ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi ti ṣe isọmọlorukọ ọmọbinrin tuntun ti Eleduwa fi ta oun ati iyawo Olori rẹ lọrẹ.

Oluwo funraraẹ lo ṣe isọmọlorukọ naa, laarin awọn Ọba alaye mii, awọn adari ẹsin, olori ilu atawọn afẹnifẹre, Oluwo fi orukọ ọmọ naa sọri Olofin Adimula tii ṣe Obinrin kanṣoṣo to jọba ni Ile Ife, iyẹn “Luwo Gbagida”.

Luwo Gbagida ni obinrin kanṣoṣo to jọba ni ile Ife to si tun jẹ iya to bi Adekola Telu ẹni to tẹ ilu Iwo do ni igba iwasẹ.

“Orukọ ọmọ naa yoo si maa jẹ:

Oluwo ṣe apejuwe Luwo Gbagida gẹgẹ bii akọni, onigboya ati eeyan to ni afojusun gẹgẹ bi Ọbabinrin akọkọ jakejado agbaye.

Ninu atẹjade kan ti Oluwo fi sita latọwọ akọwe rẹ, Alli Ibraheem jẹ ko di mimọ pe “Lonii, mo n kọ itan nla kan nipa fifi orukọ ọmọ sọri Obinrin ara ọtọ, Iya wa, Luwo Gbagida”.

“Luwo Gbagida ni obinrin kanṣoṣo to jẹ Olofin Adimula ti Ile Ife. Igboya gidi to ni ati ipa rere to ti ko lo gbe ilu Iwo jade. O gbe ade fun ọmọ rẹ ọkunrin kanṣoṣo, Adekola Telu lati tẹ ilu “otitọ (Ilu Ayekooto), Iwo do.

Ọba Abdulrosheed ṣalaye pe ipinu Ọbabinrin naa to fi mọ ipamọra ti Telu ati awọn ẹmẹwa rẹ lo gbe ilu Iwo kalẹ titi di oni.

“Ọmọ iran Oduduwa tootọ ni Luwo jẹ. Oun gan ṣe bii Oduduwa bẹẹ si ni ijọba rẹ jẹ eyi ti gbogbo eniyan ni imọlara rẹ.

Oluwo ati iyawo rẹ

Oluwo ti Iwo ni oun ti ṣe awọn nnkan to jọra pẹlu Ọbabinrin yii, fun apẹrẹ: “Oun ni Olofin Adimula ikẹrindinlogun nigba ti emi naa jẹ Oluwo ikẹrindinlogun. Koda ọjọ ikẹrindinlogun ni oṣu kinni, ọdun 2016 ni ọjọ̀ iwuye mi”.

Oluwo tun ṣalaye pe ọpọlọpọ nnkan iyanu lo rọ mọ ibi ọmọ oun tuntun. “Ibi rẹ jẹ ibukun, kii ṣe fun ijọba mi nikan bikoṣe gbogbo ilẹ Yoruba tayọ ile. Ẹbun lo jẹ fun ọmọniyan”.

Gẹgẹ bo ṣe wa lori oju opo ayelujara Wikipedia, o jẹ ọmọbinrin iran Olofin Adimula Otaataa lati agbo ile Owode, Okerewe ati iran Olofin Lafogido. Oun ni akọkọ Ọba to jẹ lori ilu Ile Ife eyi ti wọn gẹgẹ bi ibi ti gbogbo ọmọ Yoruba wa.

Olofin Giesi lo gba a de lẹyin Oriade naa. Iṣejọba Olofin Luwo lo ṣi wa jẹ ijọba eyi ti obinrin jẹ ri nile Ife titi di oni.

Ọmọ rẹ, Adekola Telu lo wa tẹ ilu Iwo do.