Gbogbo nǹkan ló ní Àkókò – Davido wú ọ̀rọ̀ síta nípa ìṣẹ̀lẹ̀ aburú tó já lù ú

David Adeleke

Oríṣun àwòrán, Davido/Instagram

Olorin takasufee to tun jẹ ilumọọka ni Naijiria, David Adeleke, ẹni ti ọpọ mọ si Davido ti pada sori ayelujara lati bẹrẹ si ni sọrọ lẹyin ipapoda ọmọ rẹ ọkunrin, Ifeanyi Adeleke.

Davido fi ọrọ sita lori ayelujara lati ṣe afihan orin tuntun rẹ to gbe jade, tí ọpọlọpọ awọn ololufẹ rẹ si tu jade lati tẹwọgba olorin naa.

Ninu ọrọ ti Davido gbe soju opo ayelujara rẹ, o ni

“Ohun gbogbo ni akoko wa fun” , o si n dupẹ lọwọ gbogbo awọn to fi ifẹ han sii lasiko isoro to la kọja.

“Ohun gbogbo ni akoko wa fun. Akoko lati ṣọ̀fọ̀ ati akoko imularada.

“Akoko lati rẹrin ati lati jo. Akoko lati sọrọ ati akoko lati dakẹ.

“Mo dupẹ lọwọ gbogbo awọn eeyan fun ifẹ ti wọn fi han si mi.”

bí ẹ ko ba gbagbe, ọdun to kọja ni Davido ati afẹṣọna rẹ padanu ọmọ wọn ọkunrin, Ifeanyi Adeleke.

Iṣẹlẹ ibanujẹ yii waye lasiko ti igbaradi n lọ lọwọ fun eto idibo ipinlẹ Osun eyi to si mu ki idaduro tun ba ọpọlọpọ nnkan ti Davido ti ṣeto lati gbe ṣe nigba naa.

Bakan naa, ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Osun eyi ti aburo baba rẹ, Gomina Ademola Adeleke ti n du ipo gomina naa da ọwọ ipolongo wọn duro fun ọjọ bii melo kan.

Ọmọkunrin to ṣẹṣẹ pe ọdun mẹta ni Ọgunjọ, Osu Kẹwaa, ọdun 2022 ni iroyin o ku lẹyin to ri sinu omi.

Iṣẹlẹ naa waye ni ile wọn ni agbegbe Banana Island, ni ipinlẹ Eko.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko lo fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.