Wọ́n ti fohùn ráńṣẹ́ ṣáájú pé “ṣóò ní padà wálé torí a máa “disgrace ẹ”, àmọ́ àṣírí wọn rèé – Jandor PDP

Lati igba ti eto idibo gomina ti pari jakejado Naijiria paapaa nipinlẹ Eko, oludije ẹgbẹ oẹlu Peoples Democratic Party ko tii fibẹẹ sọ ero ọkan rẹ sita lẹkunrẹrẹ nipa abajade esi idbo naa.

Ẹwẹ, ninu ifọrọwanilẹwo yii to ṣe pẹlu BBC Yoruba, Abdulazeez Olajide kẹnu bọ ọrọ lori gbogbo ohun to ṣẹlẹ laarin ẹgbẹ wọn ati ohun to pe ni ete ẹgbẹ oṣelu APC lati mu ki PDP fidi janlẹ.

Olajide Jandor

“Ẹẹ ti mọ wipe ifọwọwẹwọ wa laarin awọn to wa nijọba ati baba to ṣe n jẹ ọdọọdun naa lo maa n ṣe nnkan ti ko fi ni jẹ ki PDP jawe olubori”.

Jandor na ika alebu si adari ẹgbẹ wọn kan nipinlẹ Eko wipe o ṣeeṣe ko ni ibaṣepọ pẹlu ijọba lati ma jẹ ki ẹgbẹ oẹlu PDP jawe olubori.

Jandor ni ẹ ni ijọba kin awọn janduku lẹyin ti wọn n yọ ada yọ ibọn lati da eto idibo ru.

Jandor jẹ ko di mimọ pe eto oni ilana ni eto idibo to si ni ohun aa ṣe ko tii tan ati pe ilana naa ṣi n lọ lọwọ ti oun atawọn ọmọ ẹgbẹ yoo si tẹsiwaju ninu igbesẹ lori rẹ.

Àwọn afíkun lórí ìròyìn yìí