Olubadan gba ilẹ̀kẹ̀ lọ́rùn Mogaji, ó ní kó lọ rọọ́kun nílé torí aáwọ̀ ilẹ̀ pẹ̀lú aráàlú

Aafin Olubadan

Oríṣun àwòrán, Oluban’s palace

Ọwọ́ ìbáwí Olubadan ti ilẹ̀ Ibadan, Ọba Lekan Balogun Alli Okunmade Kejì ti ba ọkan lara awọn Mogaji rẹ, Oloye Olawale Oladoja to jẹ Mogaji Akinsola gẹgẹ bi Ọba ṣe ni ko lọ rọọkun na lẹyin awọn ìgbésẹ atiniloju ti wọn ni o gbé ni ilu Akinola, ijọba ìbílẹ̀ Akinyele nipinlẹ Oyo.

Orúkọ ilu yii bọ seti igbọ awọn eniyan ni Ọjọbọ ọ̀sẹ̀ nígbà ti Mogaji naa dede fi ọwọ ọlá gba awọn araalu loju to si n sọ pe oun ti gba àṣẹ ati idajọ ile ẹjọ́ lati fihan pe kii ṣe lọ́nà to ba òfin mú ní wọn fi ta ilẹ̀ ti wọn kọ ile wọn le lori fun wọn.

Bi ẹ ko ba gbagbe wipe o tó iye igba ile ninu ilu naa ti wọn gbe tipa ti wọn si fi ọda pupa kọ maaki si wọn lara to si ni eyi ni lati fihan pe oun lo n ṣàkóso gbogbo rẹ bayii.

Igbesẹ yii lo dá àwọn to n gbe ile síta ninu ile wọn to si mu ki awọn kan sun ita gbangba mọju. Tori eyi ni wọn fi ṣe iyanṣẹlodi lọ si aafin Olubadan ni Ọjọbọ.

Oniruuru erongba lo bẹ̀rẹ̀ si ni tu jáde koda titi de ori ayélujára. Eyi lo fa ipade pajawiri to waye eyi ti Olubadan naa si wa nibẹ pẹlu lára awọn igbimọ olugbaninimọran Ọba, awọn aṣojú Mogaji Ibadan eyi ti Oloye Asimiyu Adepoju Ariori dari àti Mogaji Akinsola gaan ti ọrọ kan to fi mọ àwọn aṣojú awọn aráàlú.

Aṣẹ wo ni Olubadan pa fún Mogaji?

Nibi ipade ọhun ni ipinu ti waye lati ni ki Mogaji naa lọ rọọkun nile àtàwọn ipinu mii.

Nigba to n ba awọn oniroyin sọ̀rọ̀ lẹyin ipade naa, Oluranlowo Olubadan lórí ọrọ iroyin, Oladele Ogunsola jẹ ko di mimọ pe ilu mẹta lo faragba ninu iṣẹlẹ naa ti awọn Mogaji ilu naa si ṣàlàyé bi Mogaji Akinsola ṣe gbe iṣẹ le wọn lọwọ lati darapo mọ ọ lati gba àwọn ilẹ̀ ọhun lọwọ awọn to ni wọn ati bi wọn ṣe ja a kulẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Mogaji Akinsola ṣàlàyé fun Olubadan àtàwọn igbimọ pe oun gbiyanju titi lati yanju ọrọ naa ko to di pe oun gbe ìgbésẹ. Ó tun ni wọn gbe ẹjọ́ naa wa si aafin ti aafin sì bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ amọ ko duro di ipari ìgbésẹ aafin ko to lọ pe awọn agbofinro lati ṣe ohun to fẹ́ ti ilé ẹjọ́ si fun idile rẹ ni àṣẹ lati ni ilẹ̀ ti wọn n ja si naa.

Ashipa Olubadan to ka ohun to wa ninu ofin tọ́ka si wipe Mogaji Akinsola ko tẹle òfin “t’ori ẹjọ́ yii ti baba wa niwaju ààfin amọ ti o ko fi ìgbésẹ rẹ to aafin leti ki o to pe Ọlọpaa. Ìgbésẹ rẹ yii doju tí, o si ni ìtẹ́ Olubadan ati gbogbo ilẹ̀ Ibadan lara.

“Ó ta ẹsẹ agẹrẹ torí naa, Igbimọ ti pinu pe ki o lọ rọọkun nile. Ati pe ki o lọ tọrọ aforijin lọwọ gbogbo ẹni ti o ni lara.”

Ijoko naa ni idajọ yii yoo fa gbogbo eeyan to ku to ba kọ lati bọ̀wọ̀ fun ipo oye wọn gẹ́gẹ́ bii Baalẹ tabi Mogaji.

Bakan naa ni wọn ni iya ẹṣẹ rẹ yóò wa titi di ìgbà ti wahala to da silẹ yoo fi ni iyanju.

Àwọn ara Ibadan yarí bí Mọgaji kan ṣe ti ọ̀pọ̀ ilé pa, wọ́n gbé
ìfẹ̀hónúhàn lọ sí ọ́físì Gómínà

Aworan

Ni owurọ Ọjọbọ ni ọgọrọ awọn olugbe agbegbe ijọba ibilẹ Akinyẹlẹ kọrajọpọ lati ṣe ifehonuhan lọ si ọfisi Gomina ipinlẹ Ọyọ, to n bẹ ni agbegbe Agodi ni ilu Ibadan, lẹyin ti ọpọlọpọ wọn ti ibi iṣẹ de ni Ọjọru ti wọn si dede ba ọkanojọkan agadagodo lẹnu ọna ile wọn.

Iroyin ti wọn gbọ ni pe ọkan lara awọn Mọgaji ilẹ Ibadan ti wọn jọ n fa ọrọ ilẹ lo gbe igbesẹ naa. Onka ile ti Magaji naa si tipa le ni igba gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

Họnọrebu Ọlatunde Kehinde to n ṣoju ẹkun idibo keji ni ijọba ibilẹ Akinyẹle lo jade si awọn olufẹhonuhan naa. O ni ori redio ni oun ti kọkọ gbọ iroyin wi pe Mọgaji kan ti ọpọlọpọ ile pa ni ijọba ibilẹ ti o n ṣoju fun, lai mọ wi pe ile iya oun gan wa lara awọn ile ti wọn ti pa.

O ni igbesẹ akọkọ ni lati kan si olu ileeṣẹ ọlọpaa ni agbegbe naa lati le wa ojutu si ọrọ naa nipa jijiroro pẹlu Kọmisana ajọ Ọlọpaa n’ipinlẹ Ọyọ.

Kehinde ni oun ko mọ Mọgaji to ṣiṣẹ naa, bẹẹ sini oun ko ni nọmba ẹrọ ilewọ rẹ, ṣugbọn oun yoo gbe igbesẹ lati rii pe ọrọ naa tẹnubodo.

Aworan

Awọn olugbe agbegbe naa to ba akọroyin wa sọrọ fi igbe ta wi pe ile ẹjọ kankan koba wọn da si ọrọ ilẹ ri de ibi ti ọrọ yoo ti pa wọn pọ pẹlu Mọgaji to n fi ọwọ sọya wi pe oun l’oun ni ilẹ gbogbo agbegbe naa.

Nigba ti wọn ko ọrọ naa de aafin Olubadan ti ilẹ Ibadan, Ọba Lekan Balogun ke si Mọgaji naa lati gbọ tẹnu rẹ, alaye ti o si ṣe ni pe oun kan fi igbesẹ naa dẹru ba awọn olugbe agbegbe naa ni.

BBC Yoruba kan si ẹni ti wọn fi ẹsun kan, Mọgaji Wale Ọladọja ti o jẹ Mọgaji ile Akinṣọla n’ijọba ibilẹ Akinyẹlẹ, alaye ti o ṣe ni wi pe ki oun to di Mọgaji ni ọrọ ilẹ naa ti wa nilẹ. O fi kun ọrọ rẹ wi pe ija ajogunba ni ija ilẹ naa to n bẹ ni agbegbe Labi ni ijọba ibilẹ Akinyẹlẹ.

Mọgaji naa ni ilẹ baba awọn ni ilẹ agbegbe naa lati ilẹ wa, ki o to di pe awọn ọdaran kan bẹrẹ sini ta ilẹ naa fun ọpọpọlọ awọn olugbe to kọle wọn ibẹ titi di asiko yii.

Ọladọja ni pupọ awọn aṣiwaju ninu ẹbi awọn lo ti gbe igbesẹ lati gba aṣẹ ile ẹjọ ni igba marun un ọtọọtọ lori ọrọ yii, ṣugbọn pabo ni igbiyanju wọn ja si. Eyii lo mu ki oun naa tun pa kun igbiyanju wọn lati gba ilẹ ati ẹtọ awọn baba wọn pada.

Aworan

O tẹsiwaju wi pe igbesẹ ti awọn gbe l’Ọjọru lo waye nipasẹ aṣẹ ile ẹjọ ati ajọṣepo awọn agbofinro. Lodi si iroyin to n lọ kaakiri wi pe wọn ti awọn eeyan mọle ni agbegbe naa, Magaji Ọladọja ni awọn ọgba ilẹ ti wọn ko tii kọlẹ si nikan ni awọn sọ agadagodo si ti awọn si fa maaki si ara awọn ile ti wọn kọ si ori ilẹ ti awọn eeyan si n gbe ni agbegbe naa.

Ọladọja ni, “Ọna abayọ si ọrọ to wa nilẹ yii ni ki a jọ joko yika tabili ki a si sọ asọyepọ nitori eniyan ṣaa ni gbogbo wa. Mo ti pe gbogbo wọn si ipade saaju asiko yii. Nigba ti ko wa loju ti awọn ẹbi wa ro pe boya mo ti gba nnkan kan lọwọ wọn ni mo fi n tẹ ọrọ yii ri, ni awa naa fi gba ile ẹjọ lọ.”

Aworan

O ni gbogbo awọn to ṣi ilẹ naa ta ni ile ẹjọ pe sita ti wọn si da wọn lẹbi ki to di pe ile ẹjọ fun idile to ni ilẹ naa ni aṣẹ lati lọ ṣe ohun ti o tọ.

Ohun ti Mogaji naa ati mọlẹbi rẹ si fẹ bayii ni asọyepo pẹlu awọn ti ofin ni wọn ra ilẹ lọna aitọ.

Ọladẹjọ ke si awọn to n ṣe ifẹhonuhan lati tẹwọ gba alaafia ati asọyepọ ki ọrọ naa le ni iyanju.

Bakan naa ni Magaji naa ṣe alaye wi pe ipade kan yoo waye lori ọrọ ilẹ naa l’ọjọ Aiku l’aafin Olubadan ti ilẹ Ibadan.