Ìdí tí Gómìnà Adeleke ṣe yan olùdámọ̀ràn fún ‘government house pool’ ní ìpínlẹ̀ Osun – Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun

Aworan Gomina Ademola Adeleke

Oríṣun àwòrán, Osun Govt

Ni Ọjọbọ ni iroyin kan bẹrẹ si ni ja ranyinranyin lori iwe kan ti ijba ipinlẹ Ọṣun kọ lati fi yan eeyan kan si ipo olubadamọran agba nibẹ.

Ede oyinbo ti wọn fi kọ ipo naa, ‘government house pool’ jẹ ki ọpọlọpọ o maa bere idi ti wọn tun fi n yan olubadamọran lori omi nitori itumọ ti ọpọ fun ede oyinbo naa ni.

Agbẹnusọ Gomina ipinlẹ Osun, Olawale Rasheed ti tan mọle si ọhun to kede pe Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke yan oludamọran tuntun fun “Government House Pool”

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, Rasheed Ọlawale salaye pe ọpọ eeyan lo ṣi ọrọ naa gbọ nitori aini imọ to kuna nipa awọn akanlo ede ile ijọba kaakiri.

“Awọn eeyan ko mọ itumọ nnkan ti a n sọ ni, Ki i se Swimming Pool, omi adagun.

“Ẹka kan wa ninu ile ijọba to n ri si awọn awakọ ọkọ ijọba, pupọ awọn awakọ lo jẹ osisẹ ijọba.”

O ni gomina Adeleke yan oloselu kan lati mojuto bi awọn nnkan yoo ṣe maa lọ daradara lẹka naa paapaajulọ bi o ṣe jẹ wi pe owo gọbọi ni ijọba n na fi ra awọn ọkọ wọnyii.

Alhaji Oyetunji Abefe ni Gomina ipinlẹ Osun yan lati jẹ alaarina laarin awọn awakọ ninu ile ijọba ati Gomina.

Idi ti Gomina fi yan Oludamóran lori Ọkọ ninu ile ijọba

Aworan iwe naa

Oríṣun àwòrán, other

Rasheed tẹsiwaju ninu atẹjade kan to fi ransẹ si awọn akọroyin pe erongba Gomina Ademola Adeleke ni lati mojuto gbogbo ọkọ ti ijọba ra ati paapa awọn ti wọn mojuto ọkọ yii.

Gomina ni pupọ awọn lo si Gomina gbọ lori igbesẹ naa.

“Gomina gbe igbesẹ yii lati moju to awọn awakọ ati awọn ọkọ to wa ninu ile ijọba .

“Ẹ wo iye owo ti a n fi ra ọkọ, ti a wa ba ra mọto ọhun tan, ki a wa na bikita fun awọn to n se amojuto awọn ọkọ yii, Ijọba padanu niyẹn

“Ni Kano, Gomina wọn sẹsẹ yan awọn oludamọran fun Gomina lori GSM nitori onisowo GSM pọ nipinlẹ naa.

“Ti a ba se iyẹn ni isalẹ yii, awọn eeyan ma pariwo, a ko ni gbogbo nnkan bayẹn”

Wo awọn ipo aramọnda ti ijọba ti gbe sita tẹlẹ ri

Nipinlẹ Kano, labẹ ijọba Gomina Abdullahi Ganduje yan oludamọran fun Gomina lori gbogbo nnkan to ba jẹ mọ itẹ oku.

Bakan naa ni Gomina tun ni oludamọran lori ina mọnamọna oju popo lati mojuto ina mọnamọna loju popo nipinlẹ Kano.

Lọdun 2017, Gomina ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha da ẹka ijọba ti yoo ma ri si idunu awpn ẹka yooku nipinlẹ maa

Nipinlẹ Bauchi, Gomina Bala Mohammed yan oludamọran lori awọn eeyan ti igbeyawo wọn ti tuka