Ilé ẹjọ́ fẹ́sùn ìpànìyàn kan nọ́ọ̀sì tó pa ọmọdé jòjòló méje

Lucy Letby

Oríṣun àwòrán, SWNS

Ilé ẹjọ́ kan ní orílẹ̀ èdè United Kingdom ti ní nọ́ọ̀sì kan Lucy Letby jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó pa àwọn ọmọdé jòjòló méje.

Ẹ̀sùn yìí ló sọ Lucy Letby di ẹni tó ṣokùnfà ikú àwọn ọmọdé tó pọ̀ jùlọ ní UK lásìkò yìí.

Bákan náà ni ilé ẹjọ́ tún ní ó jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó gbèrò láti pa àwọn ọmọdé mẹ́fà mìíràn.

Ilé ẹjọ́ ní láàárín oṣù Kẹfà ọdún 2015 sí oṣù Kẹfà ọdún 2016 ló ṣekúpa àwọn ọmọdé náà nípa fífẹ́ atẹ́gùn sínú abẹ́rẹ́ tó fún àwọn ọmọ náà nígbà tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé ìwòsàn Countess of Chester Hospital.

Láti bíi ọdún mẹ́fà ni wọ́n ti wà lórí ìgbẹ́jọ́ náà tí àwọn ènìyàn sì gbàgbọ́ pé òhun ni ìgbẹ́jọ́ ìpànìyàn tó pẹ́ jùlọ ní orílẹ̀ èdè UK.

Nọ́ọ̀sì náà jìyàn gbogbo àwọn ẹ̀sùn méjìlélógún tí wọ́n fi kàn-án tó sì ní àìsí ìmọ́tótó tó péye ni ilé ìwòsàn náà ló ṣekúpa àwọn ọmọdé náà.

Ní ọjọ́ Ajé ni adájọ́ máa gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Lucy Letby.

Pascal Jones tó jẹ́ olùpẹjọ́ sọ wí pé àwọn nǹkan bíi atẹ́gùn, mílìkì máa ń di májèlé fún ara tí wọ́n bá fẹ sínú abẹ́rẹ́ àti pé Lucy mọ̀-ọ́n-mọ̀ lo ìmọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nọ́ọ̀sì láti fi pa àwọn ọmọ náà ni.

Jones ní Lucy Letby gbìyànjú lọ́pọ̀lọpọ̀ láti bo àwọn ìwà ìkà tó hù mọ́lẹ̀, tó sì máa ń lo ọgbọ́n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti hu àwọn ìwà ibi rẹ̀ láti fi pa àwọn ọmọ tí wọ́n kó sábẹ́ ìtọ́jú rẹ̀.

Adájọ́ tó wà nídìí ìgbẹ́jọ́ náà ní ìgbẹ́jọ́ náà jẹ ọ̀kan lára àwọn ẹjọ́ tó báni lọ́kàn jẹ́.

Kí ni ẹjọ́ náà dálé lórí?

Ẹ̀sùn pé Lucy Letby pa àwọn ògo wẹẹrẹ méje, tó sì tún gbèrò láti pa àwọn mẹ́wàá mìíràn ni ilé ìwòsàn Countess of Chester Hospital láàárín ọdún kan.

Láti bíi oṣù mẹ́sàn-án ni àwọn adájọ́ ti ń ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó wà níwájú wọn pé afẹ́fẹ́, mílìkì àti àwọn májèlé bíi insulin fi pa àwọn ọmọdé náà.

Àmọ́ Letby ni òun kò mọ nǹkankan nípa ikú àwọn ọmọ náà pé ètò àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn ọ̀hún àti àìsí ìmọ́tótó tó péye ló ṣokùnfà ikú àwọn ọmọ náà.

Olùpẹjọ́ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní lásìkò tí Letby bá wà lẹ́nu iṣẹ́ nìkan ni àwọn ọmọ náà ń ṣe aláìsí.

Bákan náà ló ka àwọn nǹkan mọ́kànlá tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ yìí lẹ́yìn tí àwọn òbí wọn bá ṣe àbẹ̀wò sí wọn bíi kí àwọ̀ wọn dédé yàtọ̀.

Ọmọbìnrin méjì àti ọmọkùnrin márùn-ún ni àwọn ọmọ tí wọ́n kú náà.

Méjì nínú àwọn ọmọkùnrin náà lọ jẹ́ méjì nínú àwọn ìbẹta kan.

Ta ni Lucy Letby?

Lucy Letby

Oríṣun àwòrán, Unknown

Ní ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kìíní ọdún 1990 ni wọ́n bí Lucy Letby, tí àwọn òbí rẹ̀ sì wà ní ilé ẹjọ́ gbogbo bí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ṣe ń wáyé.

Ohun ni ẹni àkọ́kọ́ nínú ẹbí rẹ̀ tí yóò kọ́kọ́ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga níbi tó ti kẹ́kọ̀ọ́ gboyè lórí ìmọ̀ nọ́ọ̀sì fún ọdún mẹ́ta ní ilé ẹ̀kọ́ gíga University of Chester.

Nínú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2011 tó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nọ́ọ̀sì ní ilé ìwòsàn Countess of Chester nínú oṣù Kìíní ọdún 2012.

Ní ọdún 2015 ló bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń mójútó àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó bá lágbára fún àwọn ọmọdé.

LUCY Letby kò sí ní ilé ẹjọ́ nígbà tí wọ́n ń ka àwọn ẹ̀sùn náà tí àwọn òbí rẹ̀ náà kò sì yọjú sílé ẹjọ́.

Ní UK, nọ́ọ̀sì kan ti lọ sí ẹ̀wọ̀n gbére rí fún pé òun náà pa àwọn ọmọdé.

Ní ọdún 1993 ni Beverly Alitt gba ìdájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére fẹ́sùn pé ó pa àwọn ọmọdé mẹ́rin tó sì gbèrò láti pa àwọn mẹ́sàn-án mìíràn nígbà tó ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn Grantham Hospital.