Olórí ìjọba China tẹ́lẹ̀, Jiang Zemin jáde láyé

Jiang Zemin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Olori ìjọba China nigba kan, Jiang Zemin, ti jáde laye lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun.

Àwọn ileeṣẹ iroyin ijọba ni China sọ pe ọsan Òjọru lo kú.

Ipa kekere kọ ni Zemin ko fún ọpọlọpọ ọdún, ninu idagbasoke orile-ede China.

Iku rẹ waye lasiko ti orisirisi iwọde alagbara n waye jakejado China, nitori isede COVID-19.

Àwọn ipa ti Jiang Zemin ko ni China

Zemin gba ìṣàkóso China lẹyin ìwọ́de to waye ni gbagede Tiananmen Square n’ilu Beijing, eyi to mu ọpọlọpọ ẹ̀mí lọ lọdun 1989.

Àwùjọ agbaye si fi iya jẹ China nitori eyi.

Iṣẹlẹ naa fà rògbòdìyàn ninu ẹgbẹ́ oṣelu Communist.

Nípasẹ̀ rẹ si ni Zemin fi gba igbega si ipo adari China.

Saaju iyansipo rẹ, oju ẹni ti ko ja fafa ni wọn fi má n wo Zemin, nitori pe o fẹ́ràn láti má ṣe nkan ni ilana to tọ.

Sugbọn wọn yan sípò nítorí ireti pe yoo da ìṣọ̀kan pada.

Labẹ isakoso rẹ, ọ̀rọ̀ ajé China l’agbara si, egbẹ́ oselu Communist di ipo agbara mú ṣinṣin, China sì wa ni ipo to yẹ ko wa lori igbelewọn àwọn orile-ede to ni agbara lagbaye.