Wo ìdí tí ẹni tí ipò Olubadan kàn fi ṣàbẹ̀wò sílé Olubadan àná

Olubadan

Oríṣun àwòrán, bbc

Ọba Olakulehin Owolabi ti oye Olubadan kan ṣe abẹwo si ile Ọba Mahood Lekan Balogun Olubadan ti ilẹ Ibadan to gbeṣe laipẹ yii.

Nigba to n ṣalaye idi abẹwo naa, Osi Balogun, Ọba Gbadamosi Adebimpe to gba ẹnu Ọba Olakulehin Owolabi sọrọ ṣalaye pe ṣaaju ki Kabiyesi Ọba Mahood Lekan Balogun to gbeṣe ni ara Kabiyesi Olakulehin ti le.

O ni “Ni bayii ti ara wọn ti mu okun lo faa ti wọn ṣabẹwo yii nitori pe ọrẹ ni awọn mejeeji jẹ.”

Osi Balogun tun ṣalaye pe igba akọkọ ree ti ẹni ti oye Olubadan kan yoo ṣe abẹwo si ile Olubadan to gbeṣe niluu Ibadan.

Ninu ọrọ ikini kaabọ rẹ, Sẹnetọ Kola Balogun to jẹ aburo Olubadan ana fi idunnu rẹ han, o si ṣapejuwe iṣejọba Ọba Mahood Lekan Balogun gẹgẹ bii eyii to mu alafia ba ilu Ibadan.

O wa rọ Ọba Owolabi Olakulehin lati jẹ ki alafia to ti n jọba niluu Ibadan tẹsiwaju lẹyin igba to ba ti de ori oye gẹgẹ bi Olubadan tuntun.

Ti ẹ ko ba gbage, lọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni gbogbo awuyewuye to ti n waye lori ẹni to yẹ ko jẹ oye Olubadan dopin lẹyin ti awọn afọbajẹ fọwọ si Owolabi Ọlakulẹhin gẹgẹ bii ọmọ oye tuntun.

Bo tilẹ jẹ pe o han kedere pe agba ti de si Olubadan to n bọ lọna ọhun latari bo ṣe rọra n tẹ kẹjẹ kẹjẹ niṣe lawọn eeyan n ki i ni mẹsan-an mẹwaa, ti wọn n ṣadura fun un pe yoo lo ipo naa pẹ.

Wayi o, igbimọ apapọ Olubadan ti ilẹ Ibadan ti fẹnu ko lati fi Ọba Olakulehin Owolabi jẹ Olubadan tuntun, amọ ko ti han daju ọjọ ti yoo tẹri gba ade Olubadan.