Màgòmágò ìdánwò WAEC sọ àwọn ilé ẹ̀kọ́ girama yìí nípinlẹ̀ Oyo sí abẹ́ òfin

Aworan Gomina Oyo

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/Twitter

Ajọ WAEC fi ofin de awọn ile ẹkọ girama aadọta n’ipinlẹ Ọyọ nitori aṣemaṣe idanwo.

Ajọ to n ṣe akoso idanwo akọjade iwe mẹwa ni ẹkun Iwọ-Oorun ilẹ adulawọ, WAEC ti fi ofin de awọn ile ẹkọ girama aadọta ọtọọtọ lori ẹsun wi pe wọn ṣe eru ninu idanwo opin ẹkọ fun ọdun 2022.

Atẹjade ti ẹka eto ẹkọ, imọ sayẹnsi ati ẹrọ igbalode n’ipinlẹ Ọyọ fi lede lo ṣe afihan onka awọn ile ẹkọ naa.

Lara awọn ile ekọ naa ni:

1 – Olodo Community Gramm Sch, Olodo, Ibadan.

2 – Community High School. Kasumu, Ajia.

3 – llupeju Community High School, Alugbo.

4 – Osegere Olukeye Community High School,
Osegere.

5 – Idi-Ito High School, Erunmu

6 – Owo Community Grammar School, Owo.

7 – Progressive Secondary Grammar School.

8 – Community Secondary Sch, Oke-Olola, Oyo.

9 – Community Grammar School, Kajorepo.

10 – Comminity High School, Ajase/Jabata,
Ogbomoso.

11 – Anglican/Methodist Secondary School I,
Ajagba, Oyo.

12 – Isepo/Ogidi Community Grammar Sch, Isepo.

13 – Ireti-Ogo Baptist College, Igboho

14 – Biokun Alaadun Community Grammar School, Ibadan.

15 – Lagbulu Memorial High School, Kisi.

16 – Urban Day Grammar School, Old Ife Road, Ibadan.

17 – Urban Day Grammar School, Ring Road, Ibadan.

18 – Ansar-Ud-Deen High Sch. Sango, Ibadan.

19 – Ikolaba High School, Agodi GRA, Ibadan.

20 – Renascent High School, Aremo, Ibadan.

21 – Ori-Aje Community Secondary Sch, Kudeti, lbadan.

22 – Anglican Grammar Sch. Molete, Ibadan.

23 – Community Secondary School, Adegbayi.

24 – Community Sec. School, Bioku Aladun, Ibadan.

25 – Adekile Goodwill Gramm. Sch. Ibadan.

26 Lagelu grammar rammar School, Ibadan.

Awọn ile ẹkọ ti o jẹ aladani:

1 – Ola-David Comprehensive Coll, Badeku Egbeda, Ibadan.

2. – Mount Sinai College, Adegbayi, Ibadan.

3 – Temidire Oxford College, Monatan, Ibadan.

4 – Ibadan City Model College, Iyana Church, Ibadan.

5 – Mollyvonne College. Isale-Igbagbo, Tede.

6 – God’s Blessing College, Oyo.

7 – Graceland College, Moniya, Ibadan.

8 – Honeycomb Comprehensive College, Olukeye Town, Asejire, Ibadan.

9 – I-Flier College, Ogungbade Road, Ibadan.

10 – Sure Foundation Model High School, Aba Titi, Ibadan.

11 – International Muslim College, Saki.

12 – Life Line Comprehensive High Sch. Olopomewa, Olorunsogo, Ibadan.

13 – Tender Model School, Igidogba Babanla, Ibadan.

14 – Glorius College Amuloko, Ibadan.

15 – Igboora Secondary School, Ibarapa Central.

16 – Nawair-Ud-deen Grammar School.

17 – Igboora Damcos College, Molete-Ibadan.

18 – Benevolent College, Molete, Ibadan.

19 – Sheikh Ibrahim Model College, Ibadan.

20 – Ayobami Comprehensive High School, Odo-Oba, Ibadan.

21 – Abayomi International College, Ibadan.

22 – Bolade Model College, Owode.

23 – Shafaudeen Comprehensive College, Wakajaye, Ibadan.

24 – Patimo College, Adesola, Ibadan.

Iroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe awọn ile ẹkọ naa ti wọn fi ofin de ko ni lanfani lati fi orukọ awon akekọọ ti o fẹ kọ idanwo opin iwe mẹwa silẹ titi di igba ti ajo naa yoo yi ipinnu rẹ pada.

Ni bayii, ijọba ipinlẹ Ọyọ to fesi si igbesẹ ajọ WAEC pẹlu alaye wi pe ijọba yoo da sẹria fun awọn alakoso ile ẹkọ girama ati awọn obi ti o lọwọ si aṣemaṣe idanwo ni ipinlẹ naa.

Kọmisana fun eto ẹkọ n’ipinlẹ Ọyọ, Amofin Abiodun Abdu-Raheem lo sọ ọrọ yii di mimọ l’ọjọ Aje niluu Ibadan.

Bakan naa lo parowa si awọn adari ile ẹkọ Girama lati dẹkun iwa ibajẹ ati arumọje nibi idanwo, eleyii ti o n ti n waye ni lemo lemo ni awọn ile ẹkọ ijọba ati aladani to n bẹ n’ipinlẹ naa.

Ẹwẹ, ọkan lara awọn ẹgbẹ oṣelu alatako n’ipinlẹ Ọyọ ti bẹnu atẹ lu awuyewuye to n waye lori ọrọ eto ẹkọ n’ipinle Ọyọ.

Oludije si ipo Gomina ipinlẹ Ọyọ fẹgbẹ oṣelu ‘All Progressives Congress’, APC, Sẹnatọ Teslim Folarin ti di ẹbi ọrọ naa ru Gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ti ẹgbẹ oṣelu ‘People’s Democratic Party’, PDP.

Lasiko to n ṣe ipolongo ibo nilu Ọyọ l’ọjọ Aje, Folarin gbarata wi pe ina eto ẹkọ ti n jo ajorẹyin labẹ akoso Ṣeyi Makinde.

Yatọ si ọrọ ti o jẹ mọ arumọje ati aṣemaṣe lẹnu idanwo, o ni ikuna ijọba ipinlẹ Ọyọ ti mu ki ipinlẹ naa ja wa si ipo kẹtalelọgbọn ninu onka oṣuwọn eto ẹkọ ni Naijiria.

O kilọ fun Makinde lati ma fi iya jẹ adari ile ẹkọ Girama kankan tabi awọn obi ti o ni ọmọ nile ẹkọ ti ajọ WAEC fi ofin de.

Folarin ni kii ṣe ẹbi awọn ile ẹkọ Girama tabi ti awọn obi.
Dipo bẹẹ, o ni ki Makinde ṣe atungbeyẹwo ilana eto ẹkọ.