Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ìyàwó ilé tó fi ọmọ odó pa ìyálé rẹ̀ lójú orun

Obinrin to dúró ti odó

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Bauchi ti gbe obìnrin kan to lu iyale rẹ pa, lọ sile ẹjọ́.

Arabinrin Maryam Ibrahim ni iroyin sọ pe o fi ọmọ odó lu oloogbe Hafsat Ibrahim, iyawo ti ọkọ rẹ kọ́kọ́ fẹ, ní ori, to si yọrí si iku rẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Bauchi, Ahmed Walil, sọ pe ni abule Gar, ìjọba ibilẹ Alkaleri, ni iṣẹlẹ naa ti waye lọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2022.

Ọkọ awọn obinrin mejeeji, Ibrahim Sambo tó fi iṣẹlẹ naa to àwọn ọlọ́pàá létí sọ pe ni nkan bi ọsan ọjọ́ náà, ni iṣẹlẹ naa waye.

“Ibrahim Sambo, ẹni ogoji ọdun, lo fi ẹjọ́ sun ni agọ ọlọpaa ni Maina-maji, iyawo rẹ keji, Maryam Ibrahim, ẹni ogún ọdun, fi ọmọ odó lu iyawo akọkọ, Hafsat Ibrahim, ẹni ọdun mejilelọgbọn, ni ori.

” Wọn sare gbe obìnrin naa lọ si ileewosan ni abule Gar nitori ọgbẹ́ to ni, nibẹ ni dokita si ti kede pe o ti kú.”

Afurasí naa, Maryam, jẹwọ fun awọn ọlọpaa pe ni owurọ ọjọ kejilelogun, oṣu Kọkanla, olóògbé Hafsat, fi ẹran dindin (Tsire) kan, rán ọmọ rẹ ọkùnrin, Abdulaziz Ibrahim, to jẹ ọmọ ọdún marun-un, si oun.

” Lẹyin ti mo jẹ ẹran naa tán, inú bẹ̀rẹ̀ si ni run mi, mo sì bì.”

Ọlọ́pàá ni lẹyin eyi ni Maryam, ranṣẹ pe Faiza Hamisu, to jẹ iyawo aburo ọkọ rẹ, lati ṣàlàyé nkan to sẹlẹ fun.

“Faiza sọ fúnw pé o ṣe e ṣe ko jẹ aisan ọgbẹ́ inu lo fa a, sugbọn alaye naa ko tẹ Maryam lọrun.

” Ibinu lo fi lọ si ile ìdáná, to si gbe ọmọ odó to fi fọ́ iyaale rẹ ni ori níbi to ti n sùn ninu yàrá re. ”

Lati ọjọ naa si ni Maryam ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa fun iwadii.