Ọlọ́pàá fòfin de ìwọ́de lórí ìdájọ́ ‘tribunal’ní Kano, àwọn ọ̀dọ́ yarí

Police Nigeria

Oríṣun àwòrán, getty Images

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kano ti ṣo pe oun ko ni faye gba ifẹhonuhan kankan ni bayii ti awọn eeyan ipinlẹ ọhun n duro de idajọ igbimọ to n gbọ awuyewuye esi ibo gomina to waye nibẹ.

Kọmiṣọna ọlọpaa, Husaini Gumel lo fi ikede naa sita ni olu ọọfisi rẹ to wa niluu Kano lọjọ Aje.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọfintoto ileeṣẹ ọlọpaa fi han pe awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NNPP ati APC n mura lati fẹhonuhan lọna ati tako ijoko igbimọ to n gbọ ẹjọ naa.

Awọn ọdọ kọti ikun sdi aṣẹ ọlọpaa, gbe iwọde lọ si ile gomina

Ẹwẹ, gomina ipilẹ ọhun, Abba kabir, ti gba awọn ọdọ kan to n fẹhonuhan lalejo.

Awọn oluwọde naa kọ eti ikun si aṣẹ ọlọpaa, wọn si ko ara wọn lọ sinu ọgba ile ijọba ipinlẹ naa pẹlu oniruru akọle lọwọ wọn.

Ifẹhonuhan ọhun lo waye lẹyin wakati diẹ ti ọlọpaa kede pe ẹnikẹni ko gbọdọ ṣe iwọde kankan.

Awọn ọdọ naa, ti wọn wa labẹ asia ẹgbẹ ‘Kano State Civil Society Forum’ sọ pe idajọ ododo lawọn n fẹ lati ọdọ igbimọ to n gbọ awuyewuye eto idibo ọhun.

Gẹgẹ bii ohun ti awọn oluwọde naa sọ, adajọ igbimọ naa ti kilọ fun gbogbo awọn to n gbiyanju lati fun in ni riba lori idajọ ti yoo ṣe ki wọn jawọ.

Abba Kabir Yusuf jawe olubori ninu idibo gomina naa labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NNPP lẹyin to ni ibo ti iye rẹ jẹ 1,019,602.

Nigba ti ẹni to gbe ipo keji ninu ibo ọhun, Nasiru Gawuna, lati inu ẹgbẹ oṣelu APC ni ibo yi iye rẹ jẹ 890,705.