Mo fẹ padà sọ́dọ̀ ọkọ̀ mi tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram – Ọmọbìnrin Chibok

Aworan awọn ọmọbìnrin Chibok

Oríṣun àwòrán, others

Ọkan lara awọn ọmọ obinrin akẹkọọ il̀e ẹkọ girama awọn obinrin to wa ni ilu Chibok ni ipinlẹ Borno ti orukọ rẹ n jẹ Mary Nkeki, ni oun to wu oun bayii ni ki oun pada si ọdọ ọ̀kọ ti oun fẹ lasiko ahamọ oun ni agodo awọn Boko Haram.

Ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni Mary eyi to fihan pe bi nnkan bi ọdun mejidinlogun ni lasiko ti awọn agbebọn naa kọlu ile ẹkọ wọn.

Lọjọ Aje ọsẹ yii ni Nkeki gba itusilẹ sugbọn o ni oun ti fẹ ọkan lara ọmọ ologun Boko Haram to ti yi pada, ẹni to pe orukọ rẹ Adam.

Gẹgẹ bi Ọga agba fun ikọ ọmọ ogun to n gbogun ti awọn agbebọn Boko Haram lẹkun oke ila oorun ariwa Naijiria, Ọgagun Gold Chibusi ṣe sọ, Nkeki ni ọmọ obìnrin Chibok karunlelaadọta tí awọn ologun ti gba silẹ lọwọ Boko Haram.

“Nigba ti wọn ko awọn ọmọdebinrin yìí, wọn fi tipatipa fẹ ẹ fun ọkan lara wọn ti orukọ rẹ n jẹ Adam.

Lati igba ti a gba silẹ ni o ti bẹrẹ si ni gba itọju ni ile wosan tí wa. Bakan naa ni o yoo fa le ijọba ipinlẹ Borno lọwọ.”

Nkeki lẹyin ti wọn fa le ijọba ipinlẹ Borno lọwọ sọ fun awọn akọroyin pe oun ti bí ọmọ obìnrin meji fun Adam, ẹni to jẹ Ọlọrun ni pe.

Nígba tí wọn bẹrẹ lọwọ Nkeki boya yoo se igbeyawo, O ni ” Mo ti ní ọkọ. Adam ni ọkọ mi. A jọ sa kuro lọdọ awọn to mu wa ni.

O ni oun ati ọkọ oun to ti pada lẹyin Boko Haram sa kuro ni ahamọ Boko Haram ni Dikwa ti awọn de ibi tí awọn ọmọ ologun tí doola awọn mejeeji.

Lati igba ti wọn doola awọn mejeeji ni ipinya tí laarin oun ati Adam, ẹni tí wọn mu lọ ibi ti wọn se itọju fun awọn ọmọ ologun alakatkiti Boko Haram to ti yi pada.