Olga Carmona gbọ́ ìròyìn ikú bàbá rẹ̀ lẹ́yìn tó gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé àwọn obìnrin fún Spain

Olga Carmona

Oríṣun àwòrán, TWITTER

Níṣe ni ìbànújẹ́ ṣubú layọ̀ fún olórí ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àwọn obìnrin orílẹ̀-èdè Spain, Olga Carmona, lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè rẹ̀ gba ife ẹ̀yẹ àgbáyé àwọn obìnrin lánàá.

Carmona tó gba góòlù kan ṣoṣo tí orílẹ̀-èdè Spain fi fẹ̀yìn England janlẹ̀ gba ìròyìn pé bàbá rẹ̀ jáde láyé lẹ́yìn ìdíje ọ̀hún.

Ìròyìn ní bàbá Carmona ti ń bá àìsàn kan fínra láti ọjọ́ pípẹ́ kó tó di wí pé ó jáde láyé lọ́jọ́ Ẹtì.

Carmona kọ sójú òpó ayélujára rẹ̀ pé òun ní ìgbàgbọ́ pé inú bàbá òun dùn sí òun ní ipò tó wà.

Ó fi kun pé òun ní ìgbàgbọ́ pé bàbá òun wà lára àwọn tó fún òun ní okun láti ṣe dáradára nínú ìdíje náà.

“Mi ò mọ̀ pé mo ti gba àmì ìràwọ̀ mi kí ìdíje tó bẹ̀rẹ̀.”

Àmì ìràwọ̀ ni wọ́n máa ń fi sára aṣọ àwọn orílẹ̀-èdè tó bá gbégbá orókè nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé.

Àjọ tó ń rí sí ètò bọ́ọ̀lù ni Spain sọ lori ayélujára pé ó ṣe àwọn láàánú láti kéde ikú bàbá Olga Carmona.

Lẹ́yìn ìdíje náà ni wọ́n to túfọ̀ ikú náà fún Carmona.

Iléeṣẹ́ ìròyìn Relevo ní àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Carmona kọ̀ láti túfọ̀ náà fún nítorí kó ba le gbajumọ àṣekágbá ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé to ti n kopa ki iṣẹlẹ ọhun to waye.

Ìyá àti àwọn àbúrò rẹ̀ lọ sí Australia láti lọ ṣe kóríyá fún níbi ìdíje ọ̀hún.

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Real Madrid náà bá ẹbí Olga kẹ́dùn lórí ikú náà.