Ọkọ̀ òfurufú já lulẹ̀ ní Eko, àwọn ènìyàn farapa

Ọkọ̀ òfurufú tó já lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, NEMA

Ńṣe ni ọ̀rọ̀ di bóolọ-o-yà fún mi ní agbègbè Oba Akran ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko ní ọ̀sán ọjọ́ Ìṣẹ́gun nígbà tí ọkọ̀ òfurufú kan ṣàdédé já lulẹ̀ ní àdúgbò náà.

Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ṣe sọ lójú òpó Twitter rẹ̀, iléeṣẹ́ Airfirst Hospitalityand Tour ló ni ọkọ̀ òfurufú tí nọ́mbà ìdámọ̀ rẹ̀ jẹ́ 5NCCQ tó já lulẹ̀ náà.

NEMA ní agbègbè pápákọ̀ òfurufú Eko ni ìjàmbá náà ti wáyé.

Ní iwájú ilé epo AP àti ilé ìfowópamọ́ UBA ni ọks òfurufú náà ti já lulẹ̀ tó sì gbiná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Wọ́n ní iléeṣẹ́ àwọn, àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì Eko, iléeṣẹ́ panápaná àtàwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ mìíràn ló ti ń wá ọ̀nà láti ṣàmójútó ìjàmbá náà.

Ọkọ̀ òfurufú tó já lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, NEMA

Ọkọ̀ òfurufú tó já lulẹ̀

Oríṣun àwòrán, NEMA

Wọ́n ní awakọ̀, òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ náà àtàwọn èrò méjì ló wà nínú ọkọ̀ náà tí àwọn sì ti dóòlà wọn.

Àtẹ̀jáde kan tí àjọ panápaná Eko fi síta ní ọkọ̀ òfurufú náà jẹ́ èyí tí wọ́n fi ń ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́.

Adarí àjọ náà Adeseye Margaret ní àwọn ènìyàn mẹ́rẹ́ẹ̀rin tó wà nínú ọkọ̀ náà ni wọ́n móríbọ́ láàyè àmọ́ tí wọ́n farapa.

Margaret ní ohun gbogbo ti padà bọ̀ sípò ní agbègbè náà tí àwọn sì ti ṣe ohun gbogbo láti fi dènà ìjàmbá tó tún le ṣẹ́yọ látara ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn àwòrán tó gba orí ayélujára ṣàfihàn bí àwọn ènìyàn ṣe péjọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti pa iná ọkọ̀ òfurufú ọ̀hún lásìkò tó ń jó.