Gbogbo atótónu ti parí, ọjọ́ tí a máa gbé ìdájọ́ kalẹ̀ rèé – ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ

Obi, Tinubu àti Atiku

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ lorilẹede Naijiria ní gbogbo atótónu tó yẹ kó wáyé lórí ẹjọ́ tí olùdíje sípò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Alhaji Atiku Abubakar pè tako ìjáwé olúborí Tinubu ti parí.

Ìgbìmọ̀ adájọ́ ẹlẹ́ni márùn-ún náà ni gbogbo ètò ìgbẹ́jọ́ ti parí lẹ́yìn tí wọ́n ka àwọn àkọ́ọ́lẹ̀ tí àwọn olùpẹjọ́ pè níbi ìjókòó ìgbẹ́jọ́ tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹjọ ọdún 2023.

Alága ìgbìmọ́ ọ̀hún, Adájọ́ Haruna Tsamani sọ wí pé igbimọ oludajọ naa yoo fi ọjọ idajọ ti wọn ba yan to gbogbo ilu leti ni kété tí wọn bá ti fẹnukò lórí rẹ.

Atiku Abubakar ń pe ẹjọ́ tako bí àjọ elétò ìdìbò Naijiria, Inec ṣe kéde Bola Tinubu gẹgẹbi olubori idibo aarẹ to waye loṣu keji ọdun 2023.

Bákan náà ni olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi náà ní òun kò gbà pé Tinubu ló gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

Wọ́n ń fẹ̀sùn kàn pé màgòmágó wà nínú ètò ìdìbò náà tí wọ́n sì ń rọ ilé ẹjọ́ láti wọ́gilé ìdìbò ọhun, kí INEC gba ìwé ẹ̀rí mo yege tí wọ́n ti ṣáájú fún Tinubu kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.

Ṣaájú ni ìgbìmọ̀ náà ti ní kí gbogbo àwọn olùpẹjọ́ ìyẹn Atiku Abubakar àti Peter Obi tẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party wá sọ gbogbo ohun tí wọ́n bá ní lọ́ja Ìṣẹ́gun.

INEC, Tinubu ní kí ilé ẹjọ́ da ẹjọ́ nù

Àjọ ó ń rí sí ètò ìdìbò, INEC ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ níbi ìjòkó ìgbẹ́jọ́ tó wáyé lọ́jọ́Ìṣẹ́gun láti tako ẹjọ́ tí Atiku àti Peter Obi pè.

Agbẹjọ́rò INEC, Abubakar Mahmood sọ fún ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n gba ẹjọ́ tí àwọn pè láti da ẹjọ́ Atiku àti Peter nù wọlé.

Bákan náà agbẹjọ́rò Bola Tinubu, Wole Olanipekun ní kí ilé ẹjọ́ má gba àwọn ẹ̀rí tí àwọn tó ń takò wọ́n kọ wá síwájú ilé wọlé, kí wọ́n dà wọ́n nù nítorí wọn kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

Ohun kan náà ni agbẹjọ́rò, ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Lateef Fagbemi náà bèèrè fún nígba tí òun náà ń wí àwíjàre tirẹ̀ lórí ẹjọ́ náà.

Ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Bola Tinubu àti INEC ni Peter Obi, Labour Party, Atiku Abubakar àti ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ń pè lẹ́jọ́.

Abubakar Mahmood ní òfin ètòìdìbò ọdún 2022 kò wọ́gilé kíká èsì ìbò bí ó ṣe wà tẹ́lẹ̀, pé dandan kọ́ ni lílo ẹ̀rọ ìgbàlódé láti fi ka èsì ìbò.

Ohun tí Peter Obi àti Atiku sọ fún ilé ẹjọ́ rèé

Agbẹjọ́rò Atiku Abubakar, Chris Uche ní àwọn ibi tí àwọn kò ti faramọ́ INEC, Tinubu àti APC ni pé wọ́n mọ̀-ọ́n-mọ̀ má lo ẹ̀rọ Irev láti fi gbé èsì ìbò sórí ayélujára ni.

Uche ní káàkiri gbogbo orílẹ̀ èdè ni èyí wáyé tí kìí kan ṣe àwọn ibìkan nítorí náà ó wáyé áti gba èrú láàyè ni.

Ó ní kò sí ààyè fún ẹgbẹ́ kankan láti ṣe ìdásílẹ̀ ìpínlẹ̀ àti pé Abuja kìí ṣe ìpínlẹ̀ nítorí náà kí wọ́n má ka Abuja kún ìpínlẹ̀.

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ kankan kò ì tíì wọ́gilé èsì ìbò rí, kí wan bẹ̀rẹ̀ látorí eléyìí.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn?

Ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Keje, ọdún 2023 ni ilé ẹjọ́ ti gbọ́ gbogbo atótónu ti Atiku Abubakar àti ti Peter Obi tán pátápátá.

Àwọn ẹlẹ́rìí mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀rí mìiràn ni Atiku Abubakar kó síwájú ilé nígbà tí Peter Obi sì mú ẹlẹ́rìí mẹ́tàlá kalẹ̀.

Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo ni INEC ÀTI Bola Tinubu gbé síwájú ilé ẹjọ́ àmọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC kò mú ẹlẹ́rìí kankan wá.

Àwọn olùjẹ́jọ́, APC, INEC àti Tinubu sọ fún ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà láti da gbogbo ẹjọ́ tí àwọn olùpẹjọ́ pè nù, pé wọn kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí òfin ètò ìdìbò ọdún 2022, ẹni tí èsì ìbò kan kò bá tẹ́ lọ́rùn ní ọjọ́ mọ́kànlélógún láti pé ẹjọ́ níwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò.

Láàárín oṣù mẹ́fà ni ilé ẹjọ́ náà ní láti fi gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.