Ilé aṣòfin ṣàyẹ̀wò Adelabu, El-Rufai àtàwọn míì fún ipò mínísítà

Adelabu, Stella, El-Rufai

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni ilé aṣòfin àgbà tún tẹ̀síwájú pẹ̀lú ṣíṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn tí ààrẹ Bola Tinubu fẹ́ yàn gẹ́gẹ́ mínísítà.

Àwọn mẹ́sàn-án nínú àwọn mẹ́rìnlá tó ṣẹ́kù ni ilé ṣe àyẹ̀wò fún lónìí tí ìrètí sì wà pé ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà yóò tún tẹ̀síwájú lọ́jọ́rú.

Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n ni ètò àyẹ̀wò náà bẹ̀rẹ̀ tí ilé sì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn mẹ́rìnlá nínú àwọn méjìdínlọ́gbọ̀n tí Tinubu ti ṣaájú forúkọ wọn ṣọwọ́.

Ní báyìí, àwọn mínísítà mẹ́tàlélógún ni ilé aṣòfin ti ṣe àyẹ̀wò fún, tó sì ku àwọn márùn-ún tí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò wọn yóò tẹ̀síwájú.

Lára àwọn tí wan ṣe àyẹ̀wò fún lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun ni gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai.

Gẹ́gẹ́ bí ìṣe fún àwọn tó bá jẹ́ gómìnà tẹ́lẹ̀ rí tàbí ọmọ ilé aṣòfin tẹ́lẹ̀, wọ́n kìí bèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn àmọ́ àwọn aṣòfin kan fárígá pé ài dandan kí wọ́n bèèrè ọ̀rọ̀ lẹ́nu El-Rufai.

El-Rufai nígbà tó ń fèsì sí ìbéèrè ilé aṣòfin ní ó pọn dandan láti wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ iná mọ̀nàmọ́ná kí iná ọba le dúró iré lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Àwọn tí wọ́n ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun rèé:

  • Nasir El-Rufai
  • Dave Umahi
  • Wale Edun
  • Uche Nnaji
  • Stella Okotete
  • Adebayo Adelabu
  • Ekperikpe Ekpo
  • Hannatu Musawa
  • Musa Dangiwa

Bákan náà ni ìrètí wà pé Tinubu yóò tún fi orúkọ àwọn mìíràn tó tún fẹ́ yàn ní mínísítà ránṣẹ́ sílé nítorí àwọn ìpínlẹ̀ kan kò ì tíì ní aṣojú.

Gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe làá kalẹ̀, ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ló gbọ́dọ̀ ní aṣojú tirẹ̀ tí wọn yóò yàn gẹ́gẹ́ bí mínísítà.

Pẹ̀lú orúkọ tí Tinubu fi ṣọwọ́ sílé aṣòfin, àwọn ìpínlẹ̀ kan kò ì tíì ni aṣojú rárá, tí àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn sì ní aṣojú méjì.

Àwọn mínísítà tuntun tí ilé aṣòfin ti ṣàyẹ̀wò fún rèé

Wike, Badaru, Betta, Nkiru

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

Ní nǹkan bíi aago kan ààbọ̀ ọ̀sán ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Keje ni àyẹ̀wò àwọn tí Ààrẹ Tinubu fẹ́ yàn bíi mínísítà ní ilé aṣòfin àgbà bẹ̀rẹ̀.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wanilẹ́nuwò náà, ààrẹ ilé aṣòfi àgbà Godswill Akpabio ní ó ṣeéṣe kí àwọn ṣe àyẹ̀wò àwọn mẹ́rìndínlógún tí ààyè bá gba àwọn.

Àmọ́ lẹ́yìn-ò-rẹyìn àwọn mẹ́rìnlá ni wọ́n padà ṣe àyẹ̀wò fún nínú àwọn méjìdínlọ́gbọ̀n tí Tinubu ti ṣaájú ti forúkọ wọn ṣọwọ́.

Bí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà ṣe ń lọ ni Akpabio ní àyẹ̀wò tí àwọn ń ṣe náà kò túmọ̀ sí pé àwọn ti buwọ́lù wọ́n pé wọ́n ti di mínísítà nítorí àwọn ṣì tú máa ṣe ìwádìí mìiràn lórí wọn.

Àwọn obìnrin márùn-ún ló wà lára àwọn tí wọ́n ti ṣe àyẹ̀wò fún tí àwọn ọkùnrin sì jẹ́ mẹ́sàn-án.

Àwọn tí wọ́n ti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún nìyí:

  • Abubakar Momoh
  • Nyesom Wike
  • Professor Joseph Utsev
  • Abubakar Kyari
  • John Eno
  • Bello Goronyo
  • Abubakar Badaru
  • Yusuf Maitama
  • Abubakar Danladi
  • Uju Kennedy
  • Olubunmi Ojo
  • Nkiru Onyejeocha
  • Betta Edu
  • Iman Sulaiman Ibrahim

Mo ṣetán láti ṣe àlékún àwọn iṣẹ́ ìdàgbàsókè tí mo ṣe ní Rivers fún Nàìjíríà – Wike

Ilé aṣòfin àti Wike

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti bẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn tí Ààrẹ Tinubu fi orúkọ wọn ránṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n fẹ́ yàn gẹ́gẹ́ bí Mínísítà tí yóò bá a ṣiṣẹ́.

Ní nǹkan bíi aago kan ààbọ̀ ọ̀sán ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n oṣù Keje ni àyẹ̀wò náà bẹ̀rẹ̀.

Ẹni àkọ́kọ́ tí ilé aṣòfin lábẹ́ ìdarí Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà, Godswill Akpabio kọ́kọ́ ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún ni Abubakar Momoh láti ìpínlẹ̀ Edo.

Ilé aṣòfin kò da ìbéèrè púpọ̀ bo Abubakar Momoh nítorí pé ó ti fìgbà kan jẹ́ ọmọ ilé aṣojúṣòfin tẹ́lẹ̀ rí, lẹ́yìn tó ka àwọn ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ilé kàn ní kó forí balẹ̀ kó sì máa lọ.

Lẹ́yìn rẹ̀ ni gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike bọ́ sí iwájú àwọn aṣòfin náà fún àyẹ̀wò tirẹ̀.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀, Wike sọ àrídájú rẹ̀ pé òun kò ní já Ààrẹ Tinubu àti àwọn ọmọ Nàìjíríà kulẹ̀ tí wọ́n bá buwọ́lu ìyànsípò òun.

Wike ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ìdàgbàsókè ni òun ṣe nígbà tí òun jẹ́ gómìnà ní ìpínlẹ̀ òun àti pé afara méjìlá ni òun ṣe láàárín ọdún mẹ́rin àkọ́kọ́ tí òun lò nípò.

Ó tẹmpẹlẹmọ́ pé Tinubu kò ní kábàámọ̀ rárá pé ó yan òun gẹ́gẹ́ bí mínísítà bí àwọn aṣòfin náà bá fi lè buwọ́lu ìyànsípò náà.

Ó fi kun pé àlékún àwọn nǹkan tí òun ṣe nígbà tí òun wà ní gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers ni òun máa ṣe fún Nàìjíríà tí òun bá di mínísítà.

Lẹ́yìn tó ka àwọn ìrírí rẹ̀ tán ni ilé aṣòfin ní kó tẹríba, kó sì máa lọ láì bèrè ìbéèrè kankan lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́.

Àpapọ̀ orúkọ méjìdínlọ́gbọ̀n ni Ààrẹ Tinubu fi ránṣẹ́ sílé tí ìrètí sì wà pé ó ṣì tún máa fi àwọn orúkọ mìíràn ránṣẹ́ nítorí ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan ló yẹ kó ní aṣojú tirẹ̀.

Ní báyìí, kò ì tíì sí orúkọ ènìyàn kankan láti àwọn ìpínlẹ̀ kan, tí àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn sì ní aṣojú tó ju ènìyàn kan lọ.

Àyẹ̀wò ṣì ń lọ lọ́wọ́ lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, a ò mọ iye ènìyàn tí wọ́n máa ṣe àyẹ̀wò fún lónìí nìkan.

Ilé aṣòfin àpapọ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò f’áwọn mínísítà tuntun

Aworan

Oríṣun àwòrán, Nigeria Senate

Ile igbimọ aṣofin agba lorilẹede Naijiria yoo bẹrẹ ayẹwo fun awọn eeyan mejidinlọgbọn ti Aarẹ Bola Tinubu fa kalẹ fun ipo minisita.

Ireti si wa pe Aarẹ yoo si fi orukọ awọn miiran sọwọ si ile igbimọ aṣofin pẹlu ibamu ofin to ni ipinlẹ kọọkan gbọdọ pese minisita.

Gẹgẹ bi iṣe rẹ, awọn aṣofin apapọ yoo se ayẹwo fun awọn eeyan ti aarẹ fa kalẹ naa lati mọ boya wọn kun oju iwọn lati di ọmọ igbimọ isakoso ijọba apapọ apapọ orilẹede Naijiria.

Sẹnetọ Mohammed Ali Ndume sọ fun ileeṣẹ BBC Hausa pe ile igbimọ aṣofin kekere yoo sisẹ pọ pẹlu ile igbimọ aṣofin agba lati ri pe ayẹwo naa waye ni ilana to ba ofin orilẹede Naijiria mu.

Bakan naa, Sẹnetọ Ndume ni awọn ko ni fi akoko sofo rara ati pe pupọ awọn minista ọhun lo ti wọn ti fi igba kan ri jẹ Sẹnetọ, ti wọn ko si ni nilo ati beere ohunkohun lọwọ wọn ni ibamu pẹlu atimaaṣebọ ile naa.

O fikun pe awọn ẹsọ alabo ti bẹrẹ iwadii lori awọn eeyan naa lati ri pe ko ni si wahala kankan ti wọn ba di minisita tan.

“Ninu ero temi, ayẹwo yii ko ni nira rara nitori Aarẹ gan Sẹnetọ ni tẹlẹ, ti o si mọ nnkan ti awọn ile igbimọ aṣofin n wa nibi ayẹwo ti wọn n se fun awọn Minisita.

“Asa ni pe, to ba ti jẹ Sẹnẹtọ ri, a ko ni se ayẹwo fun ẹ, irufẹ eeyan bẹ yoo kan yọ si wa, ti yoo si ki wa.”

Wo awọn eeyan ti yoo ma ṣe ayẹwo fun ipo Minisita

Abubakar Momoh

Yusuf Maitama Tuggar

Ahmad Dangiwa

Hannah Mousawa

Uche Nnaji

Dr. Diris Anite Uzoka

David Umahi

Ezenwo Nyesom Wike

Muhammed Badaru Abubakar

Nasir El Rufai

Ekerikpe Ekpo

Nkiru Onyejiocha

Olubunmi Ojo

Stella Okotete

Uju Kennedy Ohaneye

Bello Muhammad Goronyo

Dele Alake

Lateef Fagbemi

Mohammad Idris

Olawale Edun

Waheed Adebanwp

Iman Suleman Ibrahim

Prof. Ali Pate

Prof. Joseph Usev

Abubakar Kyari

John Enoch

Abubakar Danladi