Fídíò, Olè àti aláìníṣẹ́ làwọn tó ń dojú ìjà ẹ̀sìn kọ àwọn Oníṣẹ̀ṣe – Gani Adams, Duration 5,00

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Olè àti aláìníṣẹ́ làwọn tó ń dojú ìjà ẹ̀sìn kọ àwọn Oníṣẹ̀ṣe – Gani Adams

Aarẹ Ọnakakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti fi ohun silẹ fun gbogbo awọn ẹlẹsinmiran to n tako ẹsin abalaye bayii.

Ninu ọrọ kan to ba awọn eeyan sọ ni ilu Oṣogbo, Iba Gani Adams ṣalaye pe awọn ẹsin atọhunrinwa bii Islam ati Kristẹni ni lati mọ pe ẹsin abalaye ni ẹsin ti ilẹ Yoruba ti n ṣe ki awọn ẹsin wnyii to de.

O ni egun wa lori awọn ẹlẹsin miran to ba n gbogun ti ẹsin abalaye.

O fi kun un pe, bi ẹlẹsin abalaye paapaa ba lọ n gbe ẹsin abalaye lọ si Ṣọ̀ọṣi tabi Mọṣalaṣi, egun n bẹ lori rẹ nitori pe awọn alalẹ ilẹ Yoruba ko lee yọnu si iru ẹni bẹẹ.

“Egun ni fun ẹni to ba ni oun fẹ da awọn ẹlẹsin abalaye laamu nitori pe awọn lo nilẹ ki awọn ẹsin mejeeji to de”

Ole ati ainiṣẹ lo n da awọn to ba n ja ẹsin

O ṣalaye siwaju sii pe airikanṣe lo n ba awọn to n gbogun ti ẹsin abalaye ja.

O kọminu si bi awọn imaamu ẹsin musulumi kan ni ilu Ilọrin ṣe n dun mọhuru mọ awọn oniṣẹṣe nibẹ.

“Bi ẹnikẹni ba sọ pe oun n ja ija ẹsin, ole ni, olojukokoro ati alainiṣẹ ni.”

O ni ihuwasi awọn aṣiwaju ẹsin Islam nilu Ilọrin kii ṣe ohun to bojumu rara ati pe ohun to n ta ẹrẹ ba ẹya Yoruba ni ‘ki ẹni kan maa tori ẹsin sọ pe ilu Islam ni ilu Ilọrin…ṣe o jẹ Mecca ni tabi Jedah abi Saudi Arabia.”

O ni ole ni ẹni to ba sọ pe oun fẹ ja fun Ọlọrun nitori owo ti ọpọ wọn n pa nidi ẹsin ko apo ara wọn ni wọn n ko o si.