NNPCL yóò bẹ̀rẹ̀ wíwa epo rọ̀bì ní Nasarawa

Ibudo iwapo rọbii kan ni Kolmani

Oríṣun àwòrán, NNPCL

Ileeṣẹ epo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPCL ti kede pe epo rọbi wiwa yoo bẹrẹ ni ipinlẹ Nasarawa loṣu kẹta ọdun 2023.

Adari agba ileeṣẹ NNPC, Mele Kyari ṣalaye eyi ninu atẹjade kan to fi si oju opoTwitter rẹ lẹyin to ṣe abẹwo si gomina ipinlẹ Nasarawa, Abdullahi pe, igbesẹ naa wa lara awọn eto wiwa epo rọbi lawọn agbegbe to jina si ori omi ni Naijiria.

Awari epo rọbi wiwa ni ipinlẹ Nasarawa n waye lẹyin oṣu marun un ti ti ileeṣẹ epo rọbi Naijiria, NNPCL bẹrẹ si ni wa epo ni ẹkun Kolmani laarin ipinlẹ Bauchi ati Gombe.

Kyari ṣalaye pe iwadi ti wọn ṣe fi ẹri han pe omilẹgbẹ ohun alumọni omi n bẹ ni ipinlẹ naa.

Lawọn atẹjade kan ti NNPCL fi sita  laipẹ yii, Mele Kyari tẹnumọ pataki jijara mọ akanṣe iṣẹ naa, nitori bi agbaye ṣe n fi kuro  ni ẹka epo rọbi eleyi to ti n mu adinku ba idokoowo lẹka epo rọbi.

“Iṣẹ yii gbọdọ tete di ṣiṣe ni kiakia  nitori gbogbo agbaye ti n sun kuro lara epo rọbi lilo bayii. Nigba ti a o ba fi ri dun mẹwaa si asiko yii, ko si ẹni ti yoo fẹ lati dokoowo si owo epo rọbi mọ.”

Gẹgẹ bi adari agba ileeṣẹ epo rọbi Naijiria, NNPCL naa ṣe sọ, riri ajọṣepọ ati ifọwọsowọpọ araalu pẹlu awujọ to dara ṣe pataki fun  aṣeyọri iṣẹ naa lati lee dẹkun iru wahala ti awọn agbebọn n gbe dide lẹkun Niger Delta.

Ninu ọrọ rẹ, Gomina Sule ki awọn alaṣẹ ileeṣẹ NNPCL ati ijọba apapọ Naijiria ku oriire, fun akitiyan wọn lati rii daju pe eto wiwa epo lẹkun Kolmani bẹrẹ loṣu kọkanla ọdun 2022.