Fídíò, Bola Are kẹnu bọ ọ̀rọ̀ lórí àwọn èdè orin àti ìhùwàsí àwọn Olórin ẹ̀mí lóde òní, Duration 5,22

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Bola Are Gospel Artiste: Ọlọ́run ni kí ń kìlọ̀ fún ẹni tó kọ orin “kò wo bí mo ṣe ń hùwà”

“Orin Shanku, Gbese, Já paa, Jesu máa párò lọ, inú Ọlọ́run kò dùn sí i – Bola Are

Bola Are ni “ti a ba ti wọ aṣọ ti wọn n wo gbogbo nkan ti Ọlọrun da si wa niwaju, ti a tun ge e lẹyin to fẹẹ de ibadi, nkan ti ṣe o”.

Gbajugbaja ajihinrere ati olorin ẹmi ninu ẹsin Kristẹni ni arabinrin Bola Are ti gbogbo eniyan si mọ kariile kari oko titi de awọn orilẹede ti kii ṣe Naijiria.

Lara awọn eekan to jẹ manigbagbe ninu itan Yoruba ni Mama Bola are nitori iru awọn orin to maa n kọ ti ko si fi amulu mala si i lati ọdun to ti bẹrẹ orin kikọ to si gbe awo orin rẹ akọkọ jade lọdun 1973.

Mama Bola Are

Oríṣun àwòrán, Mama Bola Are

Mama Bola Are gẹgẹ bi ọpọlọpọ ṣe mọ olorin yii si kẹnu bọ ọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba lori iru igbe aye ti awọn olorin ẹmi ti aye ode oni n gbe.

“Oo le maa kọrin ko wo bi mo ṣe n huwa, ko wo bi mo ṣe n ṣe… o ṣa n tọju mi lojoojumọ; koo si maa ka iyawo oniyawo mọle tabi gba ọkọ ọlọkọ tabi ṣe agbere”.

Mama Bola Are n sọ̀rọ̀ yii nigba to n sọ pe ọpọlọpọ igbe aye ti awọn olorin ẹmi n hu ati orin wọn gan ko wa latọdọ Ọlọrun.

“Ko sí Shanku, gbẹsẹ, gbápa, Jesu máa párò lọ, ọràn rèé o”.

Mama ni laye igba ti oun bẹrẹ orin kikọ, awọn olorin aye gan lo maa n mu ori ẹmi ti wọn fi kọ ori tiwọn.

“Wọn maa mu orin wa, wọ́n a yi i pada si ‘Tungba, si gbogbo rẹ ti yoo wa nita”.

O ni laye ode oni awọn olorin ẹmi gan ni wọn pe lati wa ba awọn olorin aye kọrin papọ, o si gba wọn nimọran gẹgẹ bi olorin ẹmi lati jawọ.