Mercy Johnson, gbajúmọ̀ òṣèré tíátà kéde pé òun ni àrùn jẹjẹrẹ, ó ti ṣiṣẹ́ abẹ àmọ́ ó tún kù lẹ́yìn fun

Aworan

Oríṣun àwòrán, others

Gbajumọ osere, Mercy Johnson Okojie ti tun kẹkẹ ọrọ lori ilera ara rẹ ati ibi arun jẹjẹrẹ ṣe n baja, ti wọn dokita si ti sọ fun pe yoo nilo lati maa lo ogun fun gbogbo asiko rẹ ti yoo lo ni ile aye.

O sọrọ ọrọ nigba to n gba alejo agba osere, Joke Sliva lori ere ounjẹ rẹ lori ayelujara, Mercy’s Menu.

Osere naa ni oun ti ṣe isẹ abẹ lori aisan naa sugbọn awọn dokita ni oun yoo si maa lo awọn ogun naa fun ọjọ pipẹ, ko da fun gbogbo asiko to ku ti yoo lo laye.

O salaye pe oun ati ọkọ oun gbe ọrọ naa saara, ti wọn ko si jẹ ko pawọn lara rara tabi sọ fun ẹnikẹni.

“N ko ti ba ẹnikẹni sọrọ pe mo ni arun jẹjẹrẹ rara ati bo ya mo ṣe isẹ abẹ. Irinajo nla ni fun emi ati idile mi. A ni ọmọ, ko da abi kẹyin mi jẹ ọmọ oṣu mẹfa nigba ti isẹlẹ na waye.

“A n sọrọ fun ara wa nigba naa pe ko si iyọnu, awa tuntun ni bayi. Ẹ jẹ ka lọ si isẹ abẹ naa. Nigba ti a de ibẹ, wọn ni maa nilo lati ma logun titi aye mi.

“A ni lati kọkọ joko. Wọn fun wa ni akoko ti mo gbọdọ lo awọn ogun mi. Ti n ba tiji, ohun akọkọ ti ma kọkọ ṣe niyen, ti wọn si sọ awọn nnkan ti yoo sẹlẹ ti n ko ba lo ogun naa.